Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 14:10-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Ìwọ ti ṣẹ́gun Édómù pẹ̀lú, ṣùgbọ́n, nísinsìn yìí ìwọ ṣe ìgbéraga. Ògo nínú ìṣẹ́gun rẹ, ṣùgbọ́n dúró nílé! Kí ni ó dé tí o fi ń wá wàhálà tí o sì fa ìṣubú rẹ àti ti Júdà pẹ̀lú?”

11. Bí ó ti wù kí ó rí Ámásíà kò ní tẹ́tí, bẹ́ẹ̀ ni Jéhóásì ọba Ísírẹ́lì sì dojúkọ ọ́. Òun àti Ámásáyà ọba Júdà kọjú sí ara wọn ní Bẹti-Ṣéméṣì ní Júdà.

12. A kó ipa ọ̀nà Júdà nípasẹ̀ Ísírẹ́lì, gbogbo àwọn ọkùnrin sì sálọ sí ilé e rẹ̀.

13. Jéhóásì ọba Ísírẹ́lì fi agbára mú Ámásáyà ọba Júdà, ọmọ Jóásì, ọmọ Áhásáyà ní Bẹti-Ṣéméṣì. Nígbà náà, Jéhóásì lọ sí Jérúsálẹ́mù, ó sì lọ wó odi Jérúsálẹ́mù lulẹ̀ láti ìlẹ̀kùn Éfúráímù sí ibi igun ìlẹ̀kùn. Ìpín kan tí ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀ta ẹsẹ̀ bàtà (600).

14. Ó mú gbogbo wúrà àti fàdákà àti gbogbo ohun tí ó rí nínú ilé tí a kọ́ fún Olúwa àti níbi ìfowópamọ́ sí nínú ààfin ọba. Ó mú àwọn ìdógò, ó sì dá wọn padà sí Ṣamáríà.

15. Fún ti ìyókù iṣẹ́ nígbà ìjọba Jéhóásì, gbogbo ohun tí ó ṣe pẹ̀lú àṣeyọrí rẹ̀, pẹ̀lú ogun rẹ̀ sí Ámásáyà ọba Júdà, ṣé a kò kọ wọ́n sí inú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Ísírẹ́lì?

16. Jéhóásì sì sinmi pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín sí Ṣamáríà pẹ̀lú àwọn ọba Ísírẹ́lì. Jéróbóámù ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.

17. Ámásáyà ọmọ Jóásì ọba Júdà gbé fún ọdún mẹ́ẹ̀dógún lẹ́yìn ikú Jéhóásì ọmọ Jéhóáhásì ọba Ísírẹ́lì.

Ka pipe ipin 2 Ọba 14