Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 13:20-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Èlíṣà kú a sì sin ín.Ẹgbẹ́ Àwọn ará Móábù máa ń wọ orílẹ̀ èdè ní gbogbo àmọ́dún.

21. Bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan ti ń sin òkú ọkùnrin kan, lójijì wọ́n rí ẹgbẹ́ àwọn oníjadì: Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ju òkú ọkùnrin náà sínú ibojì Èlíṣà. Nígbà tí ara ọkùnrin náà kan egungun Èlíṣà, ó padà wá sí ayé, ó sì dúró ní ẹsẹ̀ rẹ̀.

22. Hásáélì ọba Ṣíríà ni Ísírẹ́lì lára ní gbogbo àkókò tí Jéhóáhásì fi jọba.

23. Ṣùgbọ́n Olúwa ṣàánú fún wọn ó sì ní ìyọ́nú, ó sì fiyèsí wọn nítorí májẹ̀mú rẹ̀ pẹ̀lú Ábúráhámù, Ísákì àti Jákọ́bù. Títí di ọjọ́ òní, kì í ṣe ìfẹ́ inú rẹ̀ láti pa wọ́n run tàbí lé wọn lọ níwájú rẹ̀.

24. Hásáélì ọba Ṣíríà kú, Bẹni-Hádádì ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.

25. Nígbà náà, Jéhóásì ọmọ Jéhóáhásì gbà padà kúrò lọ́wọ́ Bẹni-Hádádì ọmọ Hásáélì àwọn ìlú tí ó ti gbà nínú ogun látọ̀dọ̀ baba rẹ̀ Jéhóáhásì. Ní ẹ̀ẹ̀mẹ́ta, Jéhóásì ṣẹ́gun rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó gba ìlú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì padà.

Ka pipe ipin 2 Ọba 13