Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 10:14-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. “Mú wọn láàyè!” ó pàṣẹ. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n mú wọn láàyè, wọ́n sì pa wọ́n ní ẹ̀bá kọ̀nga Bẹti-Ékédì, ọkùnrin méjìlélógójì. Kò sì fi ẹnìkan sílẹ̀ láìkù.

15. Lẹ́yìn ìgbà tí ó kúrò níbẹ̀, ó wá sórí Jéhónádábù ọmọ Rékábù tí ó wà ní ọ̀nà rẹ̀ láti lọ bá a. Jéhù kí i, ó sì wí pé, “Ṣé ìwọ wà ní ìbárẹ́ pẹ̀lú mi, bí èmi ti wa pẹ̀lú ù rẹ?”“Èmi wà,” Jéhónádábù dáhùn.“Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀,” Jéhù wí, “fún mi ní ọwọ́ ọ̀ rẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe pẹ̀lú, Jéhù sì ràn án ọ́ lọ́wọ́ sókè sí inú kẹ̀kẹ́.

16. Jéhù wí pé, “Wá pẹ̀lú ù mi; kí o sì rí ìtara mi fún Olúwa.” Nígbà náà ó jẹ́ kí ó gun kẹ̀kẹ́ rẹ̀.

17. Nígbà tí Jéhù wá sí Ṣamáríà, ó pa gbogbo àwọn tí a fi kalẹ̀ ní ìdílé Áhábù; ó pa wọ́n run, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa tí a sọ sí Èlíjà.

18. Nígbà náà, Jéhù kó gbogbo àwọn ènìyàn jọ, ó sì wí fún wọn pé, “Áhábù sin Báálì díẹ̀; ṣùgbọ́n Jéhù yóò sìn ín púpọ̀.

19. Nísinsìn yìí, ẹ pe gbogbo àwọn wòlíì Báálì jọ, gbogbo àwọn òjíṣẹ́ rẹ̀ àti gbogbo àlùfáà rẹ̀. Rí i wí pé, kò sí nǹkankan tí ó ń sọnù nítorí ẹ̀mi yóò rú ẹbọ ńlá fún Báálì. Ẹnìkíní tí ó bá kọ̀ láti wá, kò ní wà láàyè mọ́.” Ṣùgbọ́n Jéhù fi ẹ̀tàn ṣe é, kí ó lè pa àwọn òjíṣẹ́ Báálì run.

20. Jéhù wí pé, “ẹ pe àpẹ̀jọ ní wòyí ọ̀la fún Báálì.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kéde rẹ.

21. Nígbà náà, ó rán ọ̀rọ̀ káàkiri Ísírẹ́lì, gbogbo àwọn òjíṣẹ́ Báálì sì wá: kò sí ẹnìkan tí ó dúró lẹ́yìn. Wọ́n kún ilé tí a kọ́ fún òrìṣà títí tí ó fi kún láti ìkángun èkíní títí dé èkejì.

22. Jéhù sì sọ fún olùṣọ́ pé, “Kí ó mú aṣọ ìgúnwà wá fún gbogbo àwọn òjíṣẹ́ Báálì.” Bẹ́ẹ̀ ni ó mú aṣọ ìgúnwà jáde wá fún wọn.

Ka pipe ipin 2 Ọba 10