Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 1:3-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Ṣùgbọ́n ańgẹ́lì Olúwa wí fún Èlíjà ará Tíṣíbì pé, “Lọ sókè kí o lọ bá ìránṣẹ́ ọba Ṣámáríà kí o sì bèèrè lọ́wọ́ wọn, ‘Ṣé nítorí pé kò sí Ọlọ́run ní Ísírẹ́lì ni ẹ̀yìn fi jáde lọ ṣèwádìí lọ́wọ́ Bálísébúbù òrìṣà Ékírónì?’

4. Nítorí náà ohun tí Olúwa sọ ni èyí: ‘Ìwọ kò ní kúrò lórí ìbùsùn tí o dúbúlẹ̀ lé. Dájúdájú ìwọ yóò kú!’ ” Bẹ́ẹ̀ ni Èlíjà lọ.

5. Nígbà tí ìránṣẹ́ náà padà sí ọ̀dọ̀ ọba, ó béèrè ní ọwọ́ wọn pé, “Kí ni ó dé tí ẹ̀yin fi tètè padà wá?”

6. Wọ́n dáhùn pé, “Ọkùnrin kan wá láti pàdé wa, ó sì wí fún wa pé, ‘Ẹ padà sí ọ̀dọ̀ ọba tí ó rán an yín kí ẹ sì wí fún un pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa wí: Ṣé nítorí wí pé kò sí Ọlọ́run ní Ísírẹ́lì ni o fi ń rán àwọn ènìyàn láti lọ ṣe ìwádìí lọ́wọ́ Bálísébúbù, òrìṣà Ékírónì? Nítorí náà ìwọ kò ní fi orí ibùsùn tí ìwọ dúbúlẹ̀ lé sílẹ̀. Láìsí àníàní ìwọ yóò kú!” ’ ”

7. Ọba béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Irú ọkùnrin wo ni ó wá pàdé yín, tí ó sì sọ irú èyí fún un yín?”

8. Wọ́n dáhùn pé, “Ó jẹ́ ọkùnrin tí ó wọ ẹ̀wù onírun lára pẹ̀lú ọ̀já àmùrè aláwọ́ tí ó gbà yíká ìbàdí rẹ̀.”Ọba sì wí pé, “Èlíjà ará Tíṣíbì ni.”

9. Ó sì rán balógun pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ ogun àádọ́ta rẹ̀. Balógun náà sì gòkè tọ Èlíjà lọ, ẹni tí ó jókòó ní orí òkè, wọ́n sì wí fún un pé, “Ènìyàn Ọlọ́run, ọba wí pé, ‘Sọ̀kalẹ̀ wá!’ ”

10. Èlíjà sì dá balógun lóhùn pé, “Tí ó bá jẹ́ wí pé ènìyàn Ọlọ́run ni mí, kí iná kí ó sọ̀kalẹ̀ láti òkè ọ̀run wá kí ó sì jó ìwọ àti àwọn àádọ́ta ọkùnrin rẹ!” Nígbà náà iná náà sì sọ̀kalẹ̀ wá láti òkè ọ̀run ó sì jó balógun àti àwọn ènìyàn rẹ̀.

Ka pipe ipin 2 Ọba 1