Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 1:15-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Ańgẹ́lì Olúwa sọ fún Èlíjà pé, “Ṣọ̀kalẹ̀ lọ pẹ̀lú rẹ̀; má ṣe bẹ̀rù rẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni Èlíjà dìde ó sì ṣọ̀kalẹ̀ lọ pẹ̀lú rẹ̀ sí ọ̀dọ̀ ọba.

16. Ó sọ fún ọba pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa wí: Ṣé nítorí wí pé kò sí Ọlọ́run ní Ísírẹ́lì fún ọ láti pè ni ìwọ fi rán ìránṣẹ́ lọ sí ọ̀dọ̀ Bálísébúbù, òrìṣà Ékírónì láti lọ ṣe ìwádìí? Nítorí pé o ṣe èyí, ìwọ kò níi dìde lórí ibùsùn tí o dúbúlẹ̀ lé láìsí àní àní ìwọ yóò kú!”

17. Bẹ́ẹ̀ ó sì kú, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa tí Èlíjà ti sọ.Nítorí Áhásáyà kò ní ọmọ, Jéhórámù jẹ ọba ní ọdún kejì tí Jéhórámù ọmọ Jèhósáfátì ọba Júdà.

18. Àti ní ti gbogbo àwọn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nígbà ìjọba Áhásáyà, àti ohun tí ó ṣe, ṣe a kò ha kọ wọ́n sí inú ìwé ọdọọdún ti àwọn ọba Ísírẹ́lì?

Ka pipe ipin 2 Ọba 1