Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 34:3-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Ní ọdún kẹ́jọ ìjọba rẹ̀, nígbà tí ó sì wà ní ọ̀dọ́mọdé, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí íwá ojú Ọlọ́run Baba Dáfídì. Ní ọdún kéjìlá (12). Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wẹ Júdà àti Jérúsálẹ́mù mọ́ kúrò ní ibi gíga rẹ̀, ère òrìṣà, àti ère yíyá àti ère dídà.

4. Lábẹ́ àpẹẹrẹ àwọn pẹpẹ Bálímù ni a yí lulẹ̀, ó sì fọ́ àwọn ère sí wẹ́wẹ́, ó run àwọn pẹpẹ tí ó wà lórí rẹ̀, wọ́n sì fọ́ túútúú àti àwọn ère dídá, àwọn òrìṣà àti ère dídá. Èyí tí ó fọ́ wọn sì lùúlùú, ó sì gbọ̀n wọ́n sí orí ìsà òkú àti àwọn tí ó ń rúbọ sí wọn.

5. Ó sì sun àwọn egungun àwọn àlùfáà lórí pẹpẹ wọn, Bẹ́ẹ̀ sì ni ó sì wẹ Júdà àti Jrusálẹ́mù mọ́.

6. Ní ìlú Mánásè, Éfíráímù àti Síméónì, àní títí ó fi dé Náfítalì, àti nínú àwọn, ó tú ilé wọn yíkáyíká.

7. Ó sì wó pẹpẹ àti ère òrìṣà lulẹ̀ àti àwọn ère yíyá àti àwọn òrìṣà, ó sì gùn ó sì ti ké gbogbo àwọn ère orí pẹpẹ lulẹ̀ ní gbogbo àyíká Ísírẹ́lì. Lẹ́yìn náà ó padà sí Jérúsálẹ́mù.

8. Ní ọdún kejìdínlógún ìjọba Jósíà ni a ti wẹ ilẹ̀ náà mọ́ àti ilé Olúwa, ó sì rán Ṣáfánì ọmọ Ásálíà àti Màséíà olórí ìlú náà, pẹ̀lú Jóà, ọmọ Jóáhásì, akọ̀wé, láti tún ilé Olúwa Ọlọ́run ṣe.

9. Wọ́n sì lọ sí ọ̀dọ̀ Hílíkíyà olórí àlùfáà, ó sì fún-un ní owó náà tí ó mú wá sí ínú ilé Ọlọ́run, ti àwọn ọmọ Léfì ẹni tí ó jẹ́ aṣọ́-ẹnú-ọ̀nà-ìbòdè ti gbà láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn Ménásè Éfíráímù àti láti ọ̀dọ̀ Àwọn ìyókù Ísírẹ́lì àti ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn Júdà àti Bẹ́ńjámínì wọ́n sì padà sí Jérúsálẹ́mù.

10. Nígbà náà wọn si fi le àwọn tí ń ṣiṣẹ́ ilé lọ́wọ́, àwọn tí ń ṣe alábojútó iṣẹ́ ilé Olúwa. Àwọn ọkùnrin yìí sì san owó fún àwọn òṣìṣẹ́ tí ó ń tún ṣe, tí wọ́n sì ń ṣìṣẹ́ ní ilé Olúwa.

11. Wọ́n sì tún fi owó fún àwọn ọlọ́nà àti àwọn olùkọ́lé láti ra òkúta gbígbẹ́ àti ìtì igi fún ìsopọ̀ àti igi rírẹ́ fún ìkọ́lé tí ọba Júdà ti gbà láti tẹ́ ilé tí wọ́n ti bàjẹ́.

12. Àwọn ọkùnrin náà ṣe iṣẹ́ náà pẹ̀lú òtítọ́ lórí wọn, láti darí wọn ní Jáhátì àti Obadíà, àwọn ọmọ Léfì láti Mérárì, àti Sekaríà àti Mèsúlámù, sọ̀kalẹ̀ láti Kónátì àwọn ọmọ Léfì gbogbo tí ó ní ọgbọ̀n ohun èlò orin.

13. Wọ́n sì ní olórí àwọn aláàárù àti àwọn alábojútó gbogbo àwọn òṣìsẹ́ láti ibisẹ́ si ibisẹ́, díẹ̀ nínú àwọn ọmọ Léfì sì ní alákọ̀wé, olùtọ́jú àti olùsọ́nà.

14. Nígbà tí wọ́n mú owó náà tí wọ́n mú wá sí ilé Olúwa, Hílkíà àlùfáà sì rí ìwe òfin Olúwa tí a ti fi fún-un láti ọwọ́ Mósè.

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 34