19. Àdúrà rẹ̀ àti bí inú Ọlọ́run ṣe dùn sí àdúrà rẹ̀ àti gbogbo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ àti àìsòótọ́ àti àwọn ipò níbi tí ó kọ́ àwọn ibi gíga sí, ó sì gbé àwọn òpó Áṣérà àti àwọn òrìṣà kí ó tó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, gbogbo rẹ̀ ni a kọ sínu ìwé ìrántí àwọn aríran.
20. Mánásè sinmi pẹ̀lú àwọn bàbá rẹ̀, a sì sin ín sínú ààfin rẹ̀. Ámónì ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba
21. Ámónì jẹ́ ẹni ọdún méjìlélógún nígbà tí ó di ọba. Ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún méjì.
22. Ó ṣe búburú ní ojú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí baba a rẹ̀ Mánásè ti ṣe. Ámónì sìn ó sì rú ẹbọ sí àwọn òrìṣà tí Mánásè ti ṣe.
23. Ṣùgbọ́n kì í ṣe bí i baba a rẹ̀ Mánásè. Kò rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú Olúwa: Ẹ̀bi Ámónì ń ga sí i.
24. Àwọn onísẹ́ Ámónì dìtẹ̀ síi. Wọ́n sì pa á ní ààfin rẹ̀
25. Nígbà náà, gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà pa gbogbo àwọn tí wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Ámónì, wọ́n sì mú Jósíà ọmọ rẹ̀ jọba ní ipò rẹ̀.