Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 30:8-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Ǹjẹ́ kí ẹ̀yin kí ó má se ṣe ọlọ́rùn líle, bí àwọn baba yín, ṣùgbọ́n ẹ jọ̀wọ́ ara yín lọ́wọ́ fún Olúwa, kí ẹ sì wọ inú ibi mímọ́ rẹ̀ lọ, ti òun ti ìyà sí mímọ́ títí láé: Kí ẹ sì sin Olúwa, Ọlọ́run yín kí ìmúná ìbínú rẹ̀ kí ó lè yípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ yín.

9. Nítorí bí ẹ̀yin bá tún yípadà sí Olúwa, àwọn arákùnrin yín, àti àwọn ọmọ yín, yóò rí àánú níwájú àwọn tí ó kó wọn ní ìgbèkùn lọ, kí wọn kí ó lè tún padà wá sí ilẹ̀ yí: nítorí Olúwa Ọlọ́run yín, oníyọ́nú àti aláàánú ni, kì yóò sì yí ojú rẹ̀ padà kúrò lọ́dọ̀ yín, bí ẹ̀yin bá padà sọ́dọ̀ rẹ̀.”

10. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn onísẹ́ náà kọjá lati ìlú dé ìlú, ní ilẹ̀ Éfúráímù àti Mánásè títí dé Sébúlúnì: Ṣùgbọ́n wọ́n fi wọ́n rẹ́rín ẹlẹ́yà, wọ́n sì gàn wọ́n.

11. Síbẹ̀ òmíràn nínú àwọn ènìyàn Áṣérì àti Mánásè àti Sébúlúnì rẹ̀ ara wọn sílẹ̀, wọ́n sì wá sí Jérúsálẹ́mù.

12. Ní Júdà pẹ̀lú, ọwọ́ Ọlọ́run wá láti fún wọn ní ọkàn kan láti pa òfin ọba mọ́ àti tí àwọn ìjòyè, nípa ọ̀rọ̀ Olúwa.

13. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn sì péjọ ní Jérúsálẹ́mù, láti pa àjọ àkàrà aláìwú mọ́ ní oṣù kejì.

14. Wọ́n sì dìde, wọ́n sì kó gbogbo pẹpẹ tí ó wà ní Jérúsálẹ́mù lọ, àti gbogbo pẹpẹ tùràrí ni wọ́n kó lọ, wọ́n sì dà wọ́n sí odò Kídírónì.

15. Nígbà náà ni wọ́n pa ẹran ìrékọjá náà ní ọjọ́ kẹ́rinlà oṣù kejì: ojú sì ti àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì, wọ́n sì yà ara wọn sí mímọ́, wọ́n sì mú ẹbọ sísun wá sínú ilé Olúwa.

16. Wọ́n sì dúró ní ipò wọn, bí ètò wọn gẹ́gẹ́ bí òfin Mósè, ènìyàn Ọlọ́run: àwọn àlùfáà wọ́n ẹ̀jẹ̀ náà, tí wọ́n gbà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Léfì.

17. Nítorí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó wà nínú ìjọ ènìyàn náà tí kò yà ara wọn sí mímọ́: wọn pa ẹran ìrékọjá fún olúkúlùkù ẹni tí ó ṣe aláìmọ́, láti yà á sí mímọ́ sí Olúwa.

18. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, àni ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú Éfíráimù àti Mánásè, Ísákárì, àti Sébúlúnì kò sá wẹ̀ ara wọn mọ́ síbẹ̀ wọ́n jẹ ìrékọjá naà, kì íṣe gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́. Ṣùgbọ́n Heṣekáyà bẹ̀bẹ̀ fún wọn, wí pé, Olúwa, ẹni rere, dáríjin olúkúlùkù,

19. Tí ó múra ọkàn rẹ̀ láti wá Ọlọ́run, Olúwa Ọlọ́run àwọn baba rẹ̀ ṣùgbọ́n tí kì íṣe nípa ìwẹ̀nùmọ́ mímọ́

20. Olúwa sì gbọ́ ti Hesékíà, ó sì mú àwọn ènìyàn náà lára dá.

21. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí a rí ní Jérúsálẹ́mù fi ayọ̀ ńlá pa àjọ àkàrà aláìwú mọ́ ní ọjọ́ méje: àwọn ọmọ Léfì, àti àwọn àlùfáà yin Olúwa lójojúmọ́, wọ́n ń fi ohun èlò olóhùn gooro kọrin sí Olúwa.

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 30