Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 30:5-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n fi àṣẹ kan lélẹ̀, láti kéde ká gbogbo Ísírẹ́lì láti Beerí-sébà àní títí dé Dánì, láti wá pa àjọ ìrékọjá mọ́ sí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì ní Jérúsálẹ́mù: nítorí wọn kò pa á mọ́ ní ọjọ́ púpọ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́.

6. Bẹ́ẹ̀ àwọn oníṣẹ tí ń sáré lọ pẹ̀lú ìwé láti ọwọ́ ọba àti àwọn ìjòyè rẹ̀ sí gbogbo Ísírẹ́lì àti Júdà; àti gẹ́gẹ́ bí àṣẹ ọba, wí pé:“Ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì ẹ yí padà sí Olúwa Ọlọ́run Ábúráhámù, Ísáákì, àti Ísírẹ́lì, òun ó sì yípadà sí àwọn ìyókù nínú yín, tí ó sálà kúrò lọ́wọ́ àwọn ọba Ásíríà.

7. Kí ẹ̀yin kí ó má sì ṣe dàbí àwọn baba yín, àti bí àwọn arákùnrin yín tí ó dẹ́sẹ̀ sí Olúwa, Ọlọ́run àwọn baba wọn, nítorí náà ní ó ṣe fi wọ́n fún ìdahoro bí ẹ̀yin ti rí.

8. Ǹjẹ́ kí ẹ̀yin kí ó má se ṣe ọlọ́rùn líle, bí àwọn baba yín, ṣùgbọ́n ẹ jọ̀wọ́ ara yín lọ́wọ́ fún Olúwa, kí ẹ sì wọ inú ibi mímọ́ rẹ̀ lọ, ti òun ti ìyà sí mímọ́ títí láé: Kí ẹ sì sin Olúwa, Ọlọ́run yín kí ìmúná ìbínú rẹ̀ kí ó lè yípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ yín.

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 30