Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 30:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Hésékíà sì ránsẹ́ sí gbogbo Ísírẹ́lì àti Júdà, ó sì kọ ìwé sí Éfúráímù àti Mánásè, kí wọn kí ó wá sínú ilé Olúwa ní Jérúsálẹ́mù láti pa àjọ ìrékọjá mọ́ sí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì.

2. Nítorí tí ọba ti gbìmọ̀ àti àwọn ìjòyè rẹ̀, àti gbogbo ìjọ ènìyàn ní Jérúsálẹ́mù, láti pa àjọ ìrékọjá mọ́ ní oṣù kejì.

3. Nítorí wọn kò lè pa á mọ́ ní àkókò náà, nítorí àwọn àlùfáà kò tí i ya ara wọn sí mímọ́ tó; bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn kò tí ì kó ara wọn jọ sí Jérúsálẹ́mù.

4. Ọ̀ràn náà sí tọ́ lójú ọba àti lójú gbogbo ìjọ ènìyàn.

5. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n fi àṣẹ kan lélẹ̀, láti kéde ká gbogbo Ísírẹ́lì láti Beerí-sébà àní títí dé Dánì, láti wá pa àjọ ìrékọjá mọ́ sí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì ní Jérúsálẹ́mù: nítorí wọn kò pa á mọ́ ní ọjọ́ púpọ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́.

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 30