Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 29:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Heṣekáyà sì jẹ́ ẹni ọdún mẹẹ̀dọ́gbọ̀n (25) nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n (25) orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Ábíjà ọmọbìnrin Sékáríà.

2. Ó sì ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí bàba rẹ̀ Dáfídì ti ṣe.

3. Ní osù àkọ́kọ́ ní ọdún kìn-ín-ní ìjọba rẹ̀, ó sì sí àwọn ìlẹ̀kùn ilé Olúwa ó sì tún wọn ṣe.

4. Ó sì mú àwọn àlùfáà wá àti àwọn ọmọ Léfì, ó sì kó wọn jọ yíká ìta ìlà òorùn.

5. Ó sì wí pé, “Ẹ gbọ́ tèmi, ẹ̀yin ọmọ Léfì! Ẹ ya ara yín sí mímọ́ nísinsin yìí kí ẹ sì ya ile Olúwa Ọlọ́run sí mímọ́, kí ẹ sì kó ohun àìmọ́ bàbá jáde kúrò ní ibi mímọ́.

6. Àwọn baba wa jẹ́ aláìsòótọ́; wọ́n sì ṣe ohun àìtọ́ níwájú Olúwa Ọlọ́run wa, wọ́n sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Wọ́n sì yí ojú wọn padà kúrò ní ibùgbé Olúwa, wọ́n sì pa ẹ̀yìn wọn dà sí i.

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 29