Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 29:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Heṣekáyà sì jẹ́ ẹni ọdún mẹẹ̀dọ́gbọ̀n (25) nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n (25) orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Ábíjà ọmọbìnrin Sékáríà.

2. Ó sì ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí bàba rẹ̀ Dáfídì ti ṣe.

3. Ní osù àkọ́kọ́ ní ọdún kìn-ín-ní ìjọba rẹ̀, ó sì sí àwọn ìlẹ̀kùn ilé Olúwa ó sì tún wọn ṣe.

4. Ó sì mú àwọn àlùfáà wá àti àwọn ọmọ Léfì, ó sì kó wọn jọ yíká ìta ìlà òorùn.

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 29