Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 27:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Jótámù sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nígbà tí ó jẹ ọba, ó sì di ọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mẹ́rìndínlógun. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Jérúsà ọmọbìnrin Sádókì.

2. Ó sì ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ Ùsáyà ti ṣe, ṣùgbọ́n kìkì wí pé kò wọ ilé Olúwa. Àwọn ènìyàn síbẹ̀síbẹ̀ wọ́n ń se iṣẹ́ ibi wọn.

3. Jótanì sì kọ́ ẹnu ọ̀nà gíga ilé Olúwa ó sì ṣe iṣẹ́ lórí odi ni pẹ̀tẹ́lẹ̀ Óféli.

4. Ó sì kọ́ àwọn ìlú ní Júdà òkè àti nínú igbó àti ilé ìsọ́, ó mọ ilé odi.

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 27