Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 23:9-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Nígbà náà, ó fún àwọn alákòóso ọrọrún ní ọkọ̀ àti ńlá àti kékeré apata, tí ó jẹ́ ti ọba Dáfídì tí wọn wà ní ilé Ọlọ́run.

10. Ó mú gbogbo àwọn ọkùnrin wà ní ipò ìdúró pẹ̀lú ohun ìjà rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀, yí ọba ká ní ẹ̀bá pẹpẹ àti ilé Olúwa láti ìhà gúsù sí ìhà àríwa ilé Olúwa.

11. Jéhóiádà àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mú ọmọkùnrin ọba jáde wá wọ́n sì gbé adé sórí rẹ̀; Wọ́n mú ẹ̀dà májẹ̀mú kan fún un. Wọ́n sì kéde rẹ̀ lọ́ba. Wọ́n fi àmì òróró yàn án, wọ́n sì kígbe pé, “Kí ọba kí ó pẹ́!”

12. Nígbà tí Ataláyà gbọ́ igbe àwọn ènìyàn tí wọ́n ń sáré tí wọ́n ń kígbe ọba, ó lọ sí ọ̀dọ̀ wọn ní ilé Olúwa.

13. Ó sì wò, sì kíyèsì, ọba dúró ní ibùdúró rẹ̀ ní ẹ̀bá ẹnu-ọ̀nà, àti àwọn balógun àti àwọn afọ̀npè lọ́dọ̀ ọba, gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà sì yọ̀, wọ́n sì fọn ìpè, àti àwọn akọrin pẹ̀lú ohun èlò ìyìn, Nígbà náà ni Ataláyà fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì kégbe wí pé, “ọ̀tẹ̀! ọ̀tẹ̀!”

14. Jéhóiádà àlùfáà mú àwọn alákóso ọrọrún, tí ó wà ní àbojútó àwọn ọ̀wọ́ ogun, ó sì wá wí fún wọn pé: “Mú un jáde wá láàrin àwọn ọgbà, kí ẹ sì pa ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀le.” Nítorí tí àlùfáà ti wí pé, “Má se paá nínú ilé Olúwa.”

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 23