Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 18:6-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Ṣùgbọ́n Jehósáfátì béèrè pé, “Ṣé kò ha sí wòlíì Olúwa níbí ẹni tí àwa ìbá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀?”

7. Ọba Ìsírélì dá Jehóṣáfatì lóhùn pé, “Ọkùnrin kan wà síbẹ̀ lọ́dọ̀ ẹni tí àwa ì bá tún béèrè lọ́wọ́ Olúwa, ṣùgbọ́n èmi kórìíra rẹ̀ nítorì kò jẹ́ sọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun rere kan nípa mi ṣùgbọ́n bí kò ṣe ohun búburú, ní gbogbo ìgbà òun náà ni Míkáyà ọmọ Ímílà.”“Ọba kò gbọdọ̀ sọ bẹ́ẹ̀,” Jehóṣáfátì sì dá lóhùn.

8. Bẹ́ẹ̀ ni ọba Ísírẹ́lì pe ọ̀kan lára àwọn ìjòyè ó sì wí pé, “Ẹmú Míkáyà ọmọ Ímílà kí ó yára wá.”

9. Wọ́n wọ aṣọ Ìgúnwà wọn, ọba Ísírẹ́lì àti Jehóṣáfátì ọba Júdà wọ́n jókòó sórí ìtẹ́ wọ́n ní ìta ẹnu bodè Samaríà, pẹ̀lú gbogbo àwọn wòlíì tí ń sọtẹ́lẹ̀ níwájú wọn.

10. Nísinsin yìí Sedekáyà ọmọ Kénánà sì ti ṣe ìwo irin, ó sì wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa sọ: pẹ̀lú èyí ìwọ yóò kan àwọn ará Síríà títí ìwọ ó fi pa wọ́n run.”

11. Gbogbo àwọn wòlíì tí ó kù ni wọn ń sọtẹ̀lẹ́ ní àkókò kan náà, “Wọ́n sì wí pé, dojúkọ Rámótì Gílíádì ìwọ yóò sì ṣẹ́gun,” wọ́n wí pé, “nítorí Olúwa yóò fi lé ọba lọ́wọ́.”

12. Ìránsẹ́ tí ó ti lọ pe Míkáyà sì wí fún un pé, “Ẹ wò ó, gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin kan àti òmíràn wòlíì fi ẹnu kan sọ rere fún ọba. Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ kí ó níí ṣe pẹ̀lú ti wa, kí o sì sọ rere.”

13. Ṣùgbọ́n Míkáyà wí pe, “Gẹ́gẹ́ bí ó ti dájú pé Olúwa ń bẹ láàyè, èmi yóò sọ ohun tí Ọlọ́run mi sọ.”

14. Nígbà tí ó dé, ọba béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, “Míkáyà, se kí àwa ki ó lọ sí ogun ti Rámótì Gílíádì, tàbí kí àwa kí ó fàsẹ́yìn?”“Ẹ dojú kọ wọ́n kí ẹ sì ṣẹ́gun.” Ó dahùn, “nítorí a ó fi wọ́n lé yín lọ́wọ́.”

15. Ọba sì wí fún-un pé, “Ìgbà mélòó ni èmi ó fi ọ́ búra láti sọ ohun kan fún mi bí kò ṣe ọ̀rọ̀ òtítọ́ ní orúkọ Olúwa?”

16. Nígbà náà Míkáyà dáhùn, “Mo rí gbogbo Ísírẹ́lì fọ́n káàkiri lórí àwọn òkè, bí àgùntàn tí kò ní olùsọ́. Olúwa sì wí pé, ‘Àwọn ènìyàn wọ̀nyí kò ní ọ̀gá. Jẹ́ kí olúkúlùkù lọ sí ilé ní àlàáfíà.’ ”

17. Ọba Ísírẹ́lì wí fún Jéhóṣáfátì pé, “Ṣe èmi kò sọ fún ọ wí pé òun kò sọ àsọtẹ́lẹ̀ rere kankan nípa mi rí, ṣùgbọ́n búburú nìkan?”

18. Mikáyà tẹ̀ṣíwájú pé, “Nítorí náà, gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa: Mo rí Olúwa jòkó lórí ìtẹ́ rẹ̀ gbogbo ogun ọ̀run sì dúró lápá ọ̀tún àti lápá òsì.

19. Olúwa sì wí pé, ‘Ta ni yóò tan Áhábù ọba Ísírẹ́lì lọ sí Rámátì Giléádì kí ó sì lọ kú ikú rẹ̀ níbẹ̀?’“Èkínní sì sọ tìhín, òmíràn sì sọ tọ̀hún.

20. Ní ìparí, ni ẹ̀mí kan wá ṣíwájú, ó dúró níwájú Olúwa ó sì wí pé, ‘Èmi yóò tàn án.’“ ‘Nípa ọ̀nà wo?’ Olúwa beèrè.

21. “ ‘Èmi yóò lọ láti lọ di ẹ̀mí èké ní ẹnu gbogbo àwọn wòlíì.’ Ó wí pé.“ ‘Ìwọ yóò sì borí nínú ìtànjẹ rẹ̀ báyìí,’ ni Olúwa wí. ‘Lọ kí ó sì ṣe bẹ́ẹ̀.’

22. “Bẹ́ẹ̀ ni nísinsìn yìí Olúwa ti fi ẹ̀mí èké sí ẹnu àwọn wòlíì rẹ. Olúwa sì ti sọ ibi sí ọ.”

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 18