Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 18:32-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

32. Ó sì ṣe, nígbà tí olórí kẹ̀kẹ́ ríi wí pé kì í ṣe ọba Ísírẹ́lì, wọ́n sì dáwọ́ lílé rẹ̀ dúró.

33. Ṣùgbọ́n ẹnìkan fa ọrun rẹ̀ láì pète, ó sì bá ọba Ísírẹ́lì láàárin ìpàdé ẹ̀wù ìrin, ọba sì sọ fún olùtọ́jú kẹ̀kẹ́ rẹ̀ pé, “Yí ọwọ́ rẹ padà, kí o sì wà mí jáde kúrò lójú ìjà. Nítorí èmi ti gbọgbẹ́.”

34. Ní ọjọ́ pípẹ́, ìjà náà sì ń pọ̀ síi, ọba Ísírẹ́lì dúró nínú kẹ̀kẹ́ rẹ̀ kọjú sí àwọn ará Síríà títí ó fi di àsaálẹ́. Lẹ́yìn náà ní àkókò ìwọ oòrùn, ó sì kú.

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 18