Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 18:28-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

28. Bẹ́ẹ̀ ni ọba Ísírẹ́lì àti Jéhóṣáfátì ọba Júdà lọ sókè ní Rámótì Gílíádì.

29. Ọba Ísírẹ́lì sọ fún Jéhóṣáfátì pé, “Èmi yóò lọ sí ojú ìjà, ṣùgbọ́n ìwọ wọ aṣọ ìgunwà rẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni ọba Ísírẹ́lì pa aṣọ rẹ̀ dà, ó sì lọ sí ojú ìjà.

30. Nísinsìn yìí ọba Síríà ti pàsẹ fún àwọn olórí kẹ̀kẹ́ tí ó wà ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, “Ẹ má ṣe jà pẹ̀lú ẹnìkankan, èwe tàbí àgbà àyàfi ọba Ísírẹ́lì.”

31. Nígbà tí àwọn olórí kẹ̀kẹ́ rí Jéhóṣáfátì, wọ́n rò wí pé, “Èyí ní ọba Ísírẹ́lì.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì yípadà láti bá a jà. Ṣùgbọ́n Jéhóṣáfátì kégbe sókè, Olúwa sì ràn án lọ́wọ́. Ọlọ́run sì lé wọn kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀,

32. Ó sì ṣe, nígbà tí olórí kẹ̀kẹ́ ríi wí pé kì í ṣe ọba Ísírẹ́lì, wọ́n sì dáwọ́ lílé rẹ̀ dúró.

33. Ṣùgbọ́n ẹnìkan fa ọrun rẹ̀ láì pète, ó sì bá ọba Ísírẹ́lì láàárin ìpàdé ẹ̀wù ìrin, ọba sì sọ fún olùtọ́jú kẹ̀kẹ́ rẹ̀ pé, “Yí ọwọ́ rẹ padà, kí o sì wà mí jáde kúrò lójú ìjà. Nítorí èmi ti gbọgbẹ́.”

34. Ní ọjọ́ pípẹ́, ìjà náà sì ń pọ̀ síi, ọba Ísírẹ́lì dúró nínú kẹ̀kẹ́ rẹ̀ kọjú sí àwọn ará Síríà títí ó fi di àsaálẹ́. Lẹ́yìn náà ní àkókò ìwọ oòrùn, ó sì kú.

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 18