Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 13:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní ọdún kejìdínlógún ìjọba Jéróbóámù, Ábíjà di ọba Júdà.

2. Ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mẹ́ta. Orúkọ ìyá rẹ̀ a máa jẹ́ Mákà, ọmọbìnrin Úríélì ti Gíbéà.Ogun wà láàárin Ábíjà àti Jéróbóámù.

3. Ábíjà lọ sí ojú ogun pẹ̀lu àwọn ọmọ ogun ogún ọ̀kẹ́ (40,000) ọkùnrin alágbára, Jéróbóámù sì fa ìlà ogun sí i pẹ̀lu ogójì ọ̀kẹ́ (8,000) ọ̀wọ́ ogun tí ó lágbára.

4. Ábíjà dúró lórí òkè Ṣémáráímù ní òkè orílẹ̀ èdè Éfiráímù, ó sì wí pé, Jéróbóámù àti gbogbo Ísírẹ́lì, ẹ gbọ́ mi!

5. Ṣé ẹ̀yin kò mọ̀ pé Olúwa Ọlọ́run fún Dáfídì àti àwọn àtẹ̀lé rẹ̀ ni oyè ọba títí láé nípasẹ̀ májẹ̀mú iyọ̀?

6. Síbẹ̀ Jéróbóámù ọmọ Nébátì, oníṣẹ́ Sólómónì ọmọ Dáfídì, ṣọ̀tẹ̀ sí ọ̀gá rẹ̀.

7. Àwọn ènìyàn lásán aláìwúlò péjọ yí i ká, wọ́n sì kẹ̀yìn sí Réhóbóámù ọmọ Sólomónì ní ìgbà tí ó sì kéré tí kò lè pinnu fún ra rẹ̀, tí kò lágbára tó láti takò wọ́n.

8. “Nísinsìn yìí, ìwọ ṣètò láti kọ́ ìjọba Olúwa, tí ó wà lọ́wọ́ àwọn àtẹ̀lé Dáfídì. Ìwọ jẹ́ ọmọ ogun tí ó gbilẹ̀, ìwọ sì ní pẹ̀lu rẹ ẹgbọrọ màlúù wúrà ti Jéróbóámù dà láti se Ọlọ́run yín.

9. Ṣùgbọ́n ṣé ìwọ kò lé àwọn àlùfáà Ọlọ́run jáde, àwọn ọmọ Árónì àti àwọn ará Léfì. Tí ó sì se àwọn àlùfáà ti ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn ilẹ̀ mìíràn ti ṣe? Ẹnikẹ́ni tí ó bá wá láti ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ pẹ̀lú ọ̀dọ́ akọ màlúù àti àgbò méjì lè jẹ́ àlùfáà èyí tí kì í ṣe àwọn Ọlọ́run.

10. “Ní ti àwa, Olúwa ni Ọlọ́run wa, àwa kò sì ti ì kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Àwọn àlùfaà tí ó ń sin Olúwa jẹ́ àwọn ọmọ Árónì àwọn ará Léfì sì n ràn wọ́n lọ́wọ́.

11. Ní àràárọ̀ àti ìrọ̀lẹ́, wọ́n gbé ọrẹ sísun àti tùràrí olóòórùn dídùn síwájú Olúwa. Wọ́n gbé àkàrà jáde sórí tábìlì àsè mímọ́, wọ́n sì tan iná sí àwọn fìtílà lórí ìdúró ọ̀pá fìtílà wúrà ní gbogbo ìrọ̀lẹ́. A ń pa àṣẹ Olúwa Ọlọ́run wa mọ́. Ṣùgbọ́n ìwọ ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀.

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 13