Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 11:2-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yí wá sí ọ̀dọ̀ Ṣémáíà ènìyàn Ọlọ́run:

3. “Wí fún Rehóbóámù ọmọ Sólómónì ọba Júdà, sí gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Júdà àti Bẹ́ńjámínì,

4. ‘Èyí ní ohun tí Olúwa wí. Ẹ má ṣe gòkè lọ lati lọ jà pẹ̀lú arákùnrin yín, ẹ lọ sílé, gbogbo yín, nítorí ti ìṣe mi nìyí.’ ” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tẹ̀lé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n sì padà sẹ́yìn láti yan lọ dojúkọ Jéróbóámù.

5. Réhóbóámù ń gbe ní Jérúsálẹ́mù ó sì kọ́ àwọn ìlú fún ààbò ní Júdà.

6. Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, Étamì, Tẹ́kóà,

7. Beti-Súrì, sókò, Ádúlámù

8. Gátì, Maréṣálù Ṣífì,

9. Ádóráímù, Lákíṣì, Áṣékà

10. Ṣórà, Áíjálónì, àti Hébírónì. Wọ̀nyí ni àwọn ìlu ìdábòbò ní Júdà àti Bẹ́ńjámínì.

11. Ó sì mú àwọn ìlú olódi lágbára, ó sì fi àwọn balógun sínú wọn àti àkójọ oúnjẹ, àti òróró àti ọtí wáìnì.

12. Àti ní olúkúlùkù ìlú ni ó fi àsà àti ọ̀kọ̀ sí, ó sì mú wọn lágbára gidigidi, ó sì ní Júdà àti Bẹ́ńjámínì lábẹ́ rẹ̀.

13. Àwọn àlùfáà àti àwọn ará Léfì, láti gbogbo ẹ̀yà wọn jákè jádò Ísírẹ́lì wà ní ẹ̀bá rẹ̀.

14. Àwọn ará Léfì fi ìgbéríko sílẹ̀, wọ́n sì wá sí Júdà àti Jérúsálẹ́mù nítorí Jéróbóamù àti àwọn ọmọ rẹ̀, ti kọ̀ wọ́n sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn àlùfáà Olúwa.

15. Ó sì yan àwọn àlùfáà tirẹ̀ fún àwọn Ibi gíga àti fún ewúrẹ́ àti àwọn òrìṣà ti a gbẹ́ tí o ti ṣẹ̀.

16. Àwọn tó wá láti gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì tí wọ́n fi ọkàn wọn fún wíwá Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, tẹ̀lé àwọn ará Léfì lọ sí Jérúsálẹ́mù láti lọ rúbọ sí Olúwa Ọlọ́run bàbá a wọn.

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 11