Ó fún ìjọba Júdà ní agbára, ó sì ti Réhóbóámù ọmọ Sólómónì lẹ́yìn fún ọdún mẹ́ta nítorí ọdún mẹ́ta ni wọ́n fi rìn ní ọ̀nà ti Dáfídì àti Sólómónì ní àkókò yí.