Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 11:14-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Àwọn ará Léfì fi ìgbéríko sílẹ̀, wọ́n sì wá sí Júdà àti Jérúsálẹ́mù nítorí Jéróbóamù àti àwọn ọmọ rẹ̀, ti kọ̀ wọ́n sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn àlùfáà Olúwa.

15. Ó sì yan àwọn àlùfáà tirẹ̀ fún àwọn Ibi gíga àti fún ewúrẹ́ àti àwọn òrìṣà ti a gbẹ́ tí o ti ṣẹ̀.

16. Àwọn tó wá láti gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì tí wọ́n fi ọkàn wọn fún wíwá Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, tẹ̀lé àwọn ará Léfì lọ sí Jérúsálẹ́mù láti lọ rúbọ sí Olúwa Ọlọ́run bàbá a wọn.

17. Ó fún ìjọba Júdà ní agbára, ó sì ti Réhóbóámù ọmọ Sólómónì lẹ́yìn fún ọdún mẹ́ta nítorí ọdún mẹ́ta ni wọ́n fi rìn ní ọ̀nà ti Dáfídì àti Sólómónì ní àkókò yí.

18. Réhóbóámù fẹ́ Máhálátì tí ó jẹ́ ọmọbìnrin ọmọkùnrin Dáfídì Jérímótì àti ti Ábíháílì, ọmọbìnrin ọmọkùnrin ti Jésè Élíábì.

19. Ó bí àwọn ọmọ fún un: Jéúṣì, Ṣémáríà àti Ṣáhámì.

20. Nígbà náà ó fẹ́ Mákà ọmọbìnrin Ábúsálómù, tí ó bí Ábíjà fún Átáì, Ṣíṣà àti Ṣélómítì.

21. Réhóbóámù fẹ́ràn Mákà ọmọbìnrin Ábúsálómù ju èyí kejì nínú àwọn ìyàwó rẹ̀ àti àwọn àlè rẹ̀ lọ. Ní gbogbo rẹ̀, ó ní ìyàwó méjìdínlógún àti ọgọ́ta àlè ọmọkùnrin méjìdínlọ́gbọ̀n àti ọgọ́ta ọmọbìnrin.

22. Réhóbóámù yan Ábíjà ọmọ Mákà láti jẹ́ olóyè ọmọ aládé láàárin àwọn arákùnrin rẹ̀, kí ó ba à lè ṣe é ní ọba.

23. Ó hùwà ọlọ́gbọ́n, nípa fí fọ́nká díẹ̀ nínú àwọn ọmọ rẹ̀ jákè jádò ká àwọn agbégbé Júdà àti Bẹ́ńjámínì àti sí gbogbo àwọn ìlú ńlá aláàbò. Ó fún wọn ní ọ̀pọ̀ ohun tí wọ́n fẹ́, ó sì gba ọ̀pọ̀ ìyàwó fún wọn.

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 11