Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 9:12-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. “Ó wà,” wọ́n dáhùn. “Ó ń bẹ níwájú u yín, múra nísinsìn yìí, ó ṣẹ̀ ṣẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ wa lónìí ni, nítorí àwọn ènìyàn ní ẹbọ rírú ni ibi gíga.

13. Kété tí ẹ bá ti wọ ìlú, ẹ ó rí i kí ó tó lọ sí ibi gíga láti lọ jẹun. Àwọn ènìyàn kò sì ní bẹ̀rẹ̀ sí jẹun títí tí yóò fi dé. Torí ó gbúdọ̀ bùkún ẹbọ náà; lẹ́yìn náà, àwọn tí a pè yóò jẹun. Gòkè lọ nísinsìn yìí: ó yẹ kí ẹ rí i ní àkókò yìí.”

14. Wọ́n gòkè lọ sí ìlú náà, bí wọ́n ti ń wọlé, níbẹ̀ ni Sámúẹ́lì, ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ wọn bí ó ti ń lọ ibi gíga náà.

15. Olúwa ti sọ létí Sámúẹ́lì ní ijọ́ kan kí Ṣọ́ọ̀lù ó tó dé pé,

16. “Ní ìwòyí ọ̀la, èmi yóò ran ọmọkùnrin kan sí ọ láti ilẹ̀ Bẹ́ńjámínì. Fi òróró yàn án gẹ́gẹ́ bí olórí lórí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, yóò gba àwọn ènìyàn mi kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Fílístínì. Mo ti bojú wo àwọn ènìyàn mi, nítorí igbe wọn ti dé ọ̀dọ̀ mi.”

17. Nígbà tí Sámúẹ́lì fojú rí Ṣọ́ọ̀lù, Olúwa sọ fún un pé, “Èyí ni ọkùnrin tí mo sọ fún ọ nípa rẹ̀, yóò darí àwọn ènìyàn mi.”

18. Ṣọ́ọ̀lù sì súnmọ́ Sámúẹ́lì ní ẹnu ọ̀nà ìlú, ó sì wí pé, “Sọ fún mi èmi ń bẹ̀ ọ́ níbo ni ilé wòlíì náà wà.”

19. Sámúẹ́lì dáhùn pé, “Èmi ni wòlíì náà. Ẹ máa gòkè lọ ṣáájú mi, ní ibi gíga, ẹ ó sì bá mi jẹun lónìí. Ní òwúrọ̀ ni èmi yóò tó jẹ́ kí ẹ lọ, gbogbo ohun tí ó wà ní ọkàn rẹ ní èmi yóò sọ fún ọ.

20. Fún ti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ó sọnù fún ọjọ́ mẹ́ta sẹ́yìn, má ṣe dàamú nípa wọ́n: a ti rí wọn. Sí ta ni gbogbo ìfẹ́ Ísírẹ́lì wà? Bí kì í ṣe sí ìwọ àti sí gbogbo ilé baba à rẹ.”

21. Ṣọ́ọ̀lù dáhùn pé, “Ṣùgbọ́n èmi kì í há à ṣe ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì? Kékeré nínú ẹ̀yá Ísírẹ́lì: Ìdílé mi kò há rẹ̀yìn jùlọ nínú gbogbo ẹyà Bẹ́ńjámínì? Èésì ti ṣe tí ìwọ sọ̀rọ̀ yìí sí mi?”

22. Nígbà náà ni Sámúẹ́lì mú Ṣọ́ọ̀lù pẹ̀lú ìránṣẹ́ rẹ̀ wọ inú gbọ̀ngàn, ó sì mú wọn jókòó sí iwájú àwọn tí a pè—tí wọn tó ọgbọ̀n.

23. Sámúẹ́lì sọ fún aláṣè pé, “Mú ìpín ẹran tí mo fún ọ wá, èyí tí mo sọ fún ọ pé kí o yà sọ́tọ̀.”

24. Alásè náà sì gbé ẹṣẹ̀ náà pẹ̀lú ohun tí ó wà lórí i rẹ̀, ó sì gbé e ṣíwájú Ṣọ́ọ̀lù. Sámúẹ́lì wí pé, “Èyí ni ohun tí a fi pamọ́ fún ọ. Jẹ, nítorí a yà á sọ́tọ̀ fún ọ, fún ìdí yìí, láti ìgbà tí mo ti wí pé, ‘Mo ní àlejò tí a pè.’ ” Ṣọ́ọ̀lù sì jẹun pẹ̀lú Sámúẹ́lì ní ọjọ́ náà.

25. Lẹ́yìn ìgbà tí wọn ti sọ̀kalẹ̀ láti ibí gíga náà wá sí inú ìlú, Sámúẹ́lì sì bá Ṣọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ lórí òrùlé ilé e rẹ̀.

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 9