Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 4:3-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Nígbà tí àwọn ọmọ ogun náà padà sí ibùdó, àwọn àgbà Ísírẹ́lì sì béèrè pé, “Èéṣe ti Olúwa fi mú kí àwọn Fílístínì ṣẹ́gun wa lónìí? Ẹ jẹ́ kí a gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa láti Ṣílò wá, kí ó ba à le lọ pẹ̀lú wa kí ó sì gbàwá là kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀ta wa.”

4. Nítorí náà a rán àwọn ènìyàn lọ sí Ṣílò, wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa àwọn ọmọ ogun wá, ẹni tí ń wà láàrin àwọn Kérúbù àti àwọn ọmọ Élì méjèèjì Hófínì àti Fínéhásì wà níbẹ̀ pẹ̀lú àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run.

5. Nígbà tí àpótí ẹ̀rí májẹ̀mú Olúwa wá sí ibùdó, gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì dìde láti kígbe tó bẹ́ẹ̀ tí ilẹ̀ sì mì tìtì.

6. Ní ìgbà tí àwọn Fílístínì gbọ́ ariwo náà wọ́n béèrè pé, “Kí ni gbogbo ariwo yìí ní ibùdó Hébérù?”Nígbà tí wọ́n mọ̀ wí pé àpótí ẹ̀rí Olúwa ti wá sí ibùdó,

7. Àwọn Fílístínì sì bẹ̀rù pé, Ọlọ́run kékeré ti wọ ibùdó, wọ́n wí pé, “A wọ wàhálà, irú èyí kò tí ì ṣẹlẹ̀ rí.

8. Àwa gbé! Ta ni yóò gbà wá kúrò lọ́wọ́ Ọlọ́run alágbára yìí? Àwọn ni Ọlọ́run tí ó fi ìpọ́njú pa àwọn ará Éjíbítì pẹ̀lú gbogbo àjàkálẹ̀-àrùn ní ihà.

9. Ẹ jẹ́ alágbára Fílístínì, ẹ ṣe bí ọkùnrin, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹ̀yin yóò di ẹrú àwọn Hébérù, bí wọ́n ti jẹ́ sí i yín: Ẹ jẹ́ alágbára ọkùnrin, kí ẹ sì jagun!”

10. Nígbà náà àwọn Fílístínì jà, wọ́n sì ṣẹ́gun àwọn Ísírẹ́lì olúkúlùkù sì sá padà sínú àgọ́ rẹ̀, wọ́n pa ọ̀pọ̀ ènìyàn; Àwọn ará Ísírẹ́lì tí ó kú sí ogun sì jẹ́ ẹgbàámẹ́ẹ̀ẹ́dógún àwọn ọmọ ogun orí ilẹ̀ (30,000).

11. Wọ́n gba àpótí ẹ̀rí Olúwa, àwọn ọmọkùnrin Élì méjèèjì sì kú, Hófínì àti Fínéhásì.

12. Lọ́jọ́ kan náà tí ará Bẹ́ńjámínì kan sá wá láti ojú ogun tí ó sì lọ sí Ṣílò, aṣọ rẹ̀ sì fàya pẹ̀lú eruku lórí rẹ̀.

13. Nígbà tí ó sì dé, Élì sì jókòó sórí àga rẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà, ó ń wò, ọkàn rẹ̀ kò balẹ̀ nítorí àpótí ẹ̀rí Olúwa. Nígbà tí ọkùnrin náà wọ ìlú tí ó sì sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀, gbogbo ìlú bẹ̀rẹ̀ sí sunkún

14. Élì gbọ́ ìró ohùn ẹkún náà ó sì béèrè pé, “Kí ni ìtúmọ̀ ariwo yìí?”Ọkùnrin náà sì sáré tọ Élì wá

15. ẹni tí ó jẹ́ ẹni méjìdínlọ́gọ́run ọdún, tí ojú rẹ̀ kò sì ríran mọ́.

16. Ọkùnrin náà sọ fún Élì, “Mo ṣẹ̀ ṣẹ̀ dé láti ibi ogun náà ni: mo sá láti ibi ogun náà wá lónìí.”Élì sì béèrè pé, “Kí ni ó ṣẹlẹ̀ ọmọ mi?”

17. Ọkùnrin tí ó mú ìròyìn náà wá dáhùn pé, “Ísírẹ́lì sá níwájú àwọn Fílístínì, àwọn ọmọ ogun náà sì kú lọ́pọ̀lọpọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ méjèèjì, Hófínì àti Fínéhásì, wọ́n kú, wọ́n sì ti gba àpótí ẹ̀rí Olúwa lọ”

18. Nígbà tí ó dárúkọ àpótí ẹ̀rí Olúwa, Élì sì ṣubú sẹ́yìn kúrò lórí àga ní ẹ̀gbẹ́ bodè, ọrùn rẹ̀ ṣẹ́, ó sì kú, nítorí tí ó jẹ́ arúgbó ọkùnrin, ó sì tóbi, ó ti darí àwọn Ísírẹ́lì fún ogójì ọdún.

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 4