Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 29:6-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Ákíṣì sì pe Dáfídì, ó sì wí fún un pé, “Bí Olúwa ti ń bẹ láàyè, ìwọ jẹ́ ólóòótọ́ àti ẹni ìwà rere lójú mi, ní àlọ rẹ àti ààbọ̀ rẹ pẹ̀lú mi ní ogun: nítorí pé èmi ko tìí ri búburú kan lọ́wọ́ rẹ́ láti ọjọ́ ti ìwọ ti tọ̀ mí wá, títí o fi dì òní yìí ṣùgbọ́n lójú àwọn ìjòyè, ìwọ kò ṣe ẹni tí ó tọ́.

7. Ǹjẹ́ yípadà kí o sì máa lọ ní àlàáfíà, kí ìwọ má ṣe bà àwọn Fílístínì nínú jẹ́.”

8. Dáfídì sì wí fún Ákíṣì pé, “Kín ni èmi ṣe? Kín ni ìwọ sì rí lọ́wọ́ ìránṣẹ́ rẹ láti ọjọ́ ti èmi ti ń gbé níwájú rẹ títí di òní yìí, tí èmi kì yóò fi lọ bá àwọn ọ̀ta ọba jà.”

9. Ákíṣì sì dáhùn, ó sì wí fún Dáfídì pé, “Èmi mọ̀ pé ìwọ ṣe ẹni-rere lójú mi, bi ańgẹ́lì Ọlọ́run; ṣùgbọ́n àwọn ìjòyè Fílístínì wí pé, Òun kì yóò bá wa lọ sí ogun.

10. Ǹjẹ́, nísinsin yìí dìde ní òwúrọ pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ olúwa rẹ tí ó bá ọ wá: ki ẹ si dìde ní òwúrọ̀ nígbà tí ilẹ̀ bá mọ́ kí ẹ sì máa lọ.”

11. Dáfídì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì dìde ní òwúrọ̀ láti padà lọ sí ilẹ̀ àwọn Fílístínì. Àwọn Fílístínì sì gòkè lọ sí Jésírélì.

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 29