Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 26:1-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà náà ni àwọn ará Sífì tọ Ṣọ́ọ̀lù wá sí Gíbéà, wọn wí pé, “Dáfídì kò ha fi ara rẹ̀ pamọ́ níbi òkè Hákílà, èyí tí ó wà níwájú Jésímónì?”

2. Ṣọ́ọ̀lù sì dìde ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ijù Sífì ẹgbẹ̀ẹ́dógún àṣàyàn ènìyàn ni Ísírẹ́lì sì pẹ̀lú rẹ̀ láti wá Dáfídì ni ijù Sífì.

3. Ṣọ́ọ̀lù sì pàgọ́ rẹ̀ ní ibi òkè Hákílà tí o wà níwájú Jésímónì lójú ọ̀nà, Dáfídì sì jókòó ni ibi ijù náà, ó sì rí pé Ṣọ́ọ̀lù ń tẹ̀lé òun ni ijù náà.

4. Dáfídì sì rán àyọ́lẹ̀wò jáde, ó sì mọ nítòótọ́ pé Ṣọ́ọ̀lù ń bọ̀.

5. Dáfídì sì dìde, ó sì wá sí ibi ti Ṣọ́ọ̀lù pàgọ́ sí: Dáfídì rí ibi tí Ṣọ́ọ̀lù gbé dúbúlẹ̀ sí, àti Ábínérì ọmọ Nérì, olórí ogun rẹ̀: Ṣọ́ọ̀lù sì dùbúlẹ̀ láàrin àwọn kẹ̀kẹ́, àwọn ènìyàn náà sì pàgọ́ wọn yí i ká.

6. Dáfídì sì dáhùn, ó sì wí fún Áhímélékì, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Hétì, àti fún Ábíṣáì ọmọ Sérúíà ẹ̀gbọ́n Jóábù, pé, “Ta ni yóò ba mi sọ̀kalẹ̀ lọ sọ́dọ̀ Ṣọ́ọ̀lù ni ibùdó?”Ábíṣáì sì wí pé, “Èmi yóò ba ọ sọ̀kalẹ̀ lọ.”

7. Bẹ́ẹ̀ ni Dáfídì àti Ábíṣáì sì tọ àwọn ènìyàn náà wá lóru: sì wò ó, Ṣọ́ọ̀lù dùbúlẹ̀ ó sì ń sùn láàrin kẹ̀kẹ́, a sì fi ọ̀kọ̀ rẹ̀ gúnlẹ̀ ni ibi tìmùtìmù rẹ̀: Ábínérì àti àwọn ènìyàn náà sì dùbúlẹ̀ yí i ká.

8. Ábíṣáì sì wí fún Dáfídì pé, “Ọlọ́run ti fi ọ̀ta rẹ lé ọ lọ́wọ́ lónìí: ǹjẹ́ èmi bẹ̀ ọ́, ṣáà jẹ́ kí èmi o fi ọ̀kọ̀ gún un mọ́lẹ̀ lẹ́ẹ̀kan, èmi kì yóò gun un lẹ́ẹ̀méjì.”

9. Dáfídì sì wí fún Ábíṣáì pé, “Má ṣe pa á nítorí pé ta ni lè na ọwọ́ rẹ̀ sí ẹni àmì-òróró Olúwa kí ó sì wà láìjẹ̀bi?”

10. Dáfídì sì wí pé, “Bí Olúwa tí ń bẹ Olúwa yóò pa á, tàbí ọjọ́ rẹ̀ yóò sì pé tí yóò kú, tàbí òun ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí ibi ìjà yóò sì ṣègbé níbẹ̀.

11. Olúwa má jẹ́ kí èmi na ọwọ́ mi sí ẹni àmì òróró Olúwa: ǹjẹ́ èmi bẹ̀ ọ́, mú ọ̀kọ̀ náà tí ń bẹ níbi tìmùtìmù rẹ̀, àti ìgò omi kí a sì máa lọ.”

12. Dáfídì sì mú ọ̀kọ̀ náà àti ìgò omi náà kúrò níbi tìmùtìmù Ṣọ́ọ̀lù: wọ́n sì bá tiwọn lọ, kò sì sí ẹnìkan tí ó rí i, tàbí tí ó mọ̀: kò sì sí ẹnikàn tí ó jí; gbogbo wọn sì sùn; nítorí pé oorun ìjìká láti ọdọ Olúwa wá ti ṣubú lù wọ́n.

13. Dáfídì sì rékọjá sí ìhà kejì, ó sì dúró lórí òkè kan tí ó jìnnà réré; àlàfo kan sì wà láàrin méjì wọn:

14. Dáfídì sì kọ sí àwọn ènìyàn náà àti sí Ábínérì ọmọ Nérì wí pé, “Ìwọ kò dáhùn, Ábínérì?”Nígbà náà ni Ábínérì sì dáhùn wí pé, “Ìwọ ta ni ń pe ọba?”

15. Dáfídì sì wí fún Ábínérì pé, “Alágbára ọkùnrin kọ́ ni ìwọ bí? Ta ni ó sì dàbí ìwọ ni Ísírẹ́lì? Ǹjẹ́ èéṣe tí ìwọ kò tọ́jú ọba Olúwa rẹ? Nítorí ẹnìkan nínú àwọn ènìyàn náà ti wọlé wá láti pa ọba Olúwa rẹ.

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 26