Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 23:11-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Àwọn àgbà ìlú Kéílà yóò fi mí lé e lọ́wọ́ bí? Ṣọ́ọ̀lù yóò hà sọ̀kalẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ rẹ ti gbọ́ bí?” Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, èmi bẹ̀ ọ́, wí fún ìránṣẹ́ rẹ. Olúwa sì wí pé, “Yóò sọ̀kalẹ̀ wá.”

12. Dáfídì sì wí pé, “Àwọn àgbà ilú Kéílà yóò fi èmi àti àwọn ọmọkùnrin mi lé Ṣọ́ọ̀lù lọ́wọ́ bí?” Olúwa sì wí pé, “Wọn ó fi ọ́ lé wọn lọ́wọ́.”

13. Dáfídì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ tí wọ́n tó ẹgbẹ̀ta ènìyàn sì dìdé, wọ́n lọ kúrò ní Kéílà, wọ́n sì lọ sí ibikíbi tí wọ́n lè rìn lọ. A sì wí fún Ṣọ́ọ̀lù pé, “Dáfídì ti sá kúrò ní Kéílà; kò sì lọ sí Kéílà mọ́.”

14. Dáfídì sì ń gbé ní ihà, níbi tí ó ti sá pamọ́ sí, ó sì ń gbé níbi òkè-ńlá kan ní ihà Sífì. Ṣọ́ọ̀lù sì ń wá a lójóojúmọ́, ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò fi lé e lọ́wọ́.

15. Dáfídì sì ríi pé, Ṣọ́ọ̀lù ti jáde láti wá ẹ̀mi òun kiri: Dáfídì sì wà ní ihà Sífì nínú igbó kan.

16. Jónátanì ọmọ Ṣọ́ọ̀lù sì dìde, ó sì tọ Dáfídì lọ nínú igbó náà, ó sì gbà á ní ìyànjú nípa ti Ọlọ́run.

17. Òun sì wí fún un pé, “Má ṣe bẹ̀rù, nítorí tí ọwọ́ Ṣọ́ọ̀lù baba mi kì yóò tẹ̀ ọ́: ìwọ ni yóò jọba lórí Ísírẹ́lì, èmi ni yóò sì ṣe ibìkejì rẹ; Ṣọ́ọ̀lù baba mi mọ̀ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.”

18. Àwọn méjèèjì sì ṣe àdéhùn níwájú Olúwa; Dáfídì sì jókòó nínú igbó náà. Jónátanì sì lọ sí ilé rẹ̀.

19. Àwọn ará Sífì sì gòkè tọ Ṣọ́ọ̀lù wá sí Gíbéà, wọ́n sì wí pé, “Ṣé Dáfídì ti fi ara rẹ̀ pamọ̀ sọ́dọ̀ wa ní ibi gíga ìsápamọ́sí ní Hórésì, ní òkè Hákílà, tí ó wà níhà gúsù ti Jésímọ́nì.

20. Ǹjẹ́ nísinsin yìí, Ọba, sọ̀kalẹ̀ wá gẹ́gẹ́ bi gbogbo ìfẹ́ tí ó wà ní ọkàn rẹ láti sọ̀kalẹ̀: ipa tí àwa ní láti fi lé ọba lọ́wọ́.”

21. Ṣọ́ọ̀lù sì wí pé, “Alábùkún fún ni ẹ̀yin nípa Olúwa; nítorí pé ẹ̀yin ti káàánú fún mi.

22. Lọ, èmi bẹ̀ yín, ẹ tún múra, kí ẹ sì mọ̀ ki ẹ si rí ibi tí ẹṣẹ̀ rẹ̀ gbé wà, àti ẹni tí ó rí níbẹ̀: nítorí tí a ti sọ fún mi pé. Ọgbọ́n ni ó ń lò jọjọ.

23. Ẹ sì wo, kí ẹ sì mọ ibi ìsápamọ́ tí ó máa ń sápamọ́ sí, kí ẹ sì tún padà tọ̀ mí wá, kí èmi lè mọ̀ dájú; èmi ó sì bá yín lọ: yóò sì ṣe bí ó bá wà ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì, èmi ó sì wá a ní àwárí nínú gbogbo ẹgbẹ̀rún Júdà!”

24. Wọ́n sì dìde, wọ́n sì ṣáájú Ṣọ́ọ̀lù lọ sí Sífì: ṣùgbọ́n Dáfídì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ wà ní ihà Máónì, ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ níhà gúsù ti Jésímónì.

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 23