Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 20:10-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Dáfídì sì béèrè pé, “Ta ni yóò sọ fún mi tí baba rẹ̀ bá dá ọ lóhùn ní ohùn líle?”

11. Jónátanì wí pé, “Wá, jẹ́ kí a jáde lọ sórí pápá.” Nígbà náà wọ́n sì jáde lọ.

12. Nígbà náà ni Jónátanì sọ fún Dáfídì: “Pẹ̀lú Olúwa Ọlọ́run àwọn Ísírẹ́lì, èmi yóò rí i dájú pé mo gbọ́ ti ẹnu baba mi ní ìwòyí ọ̀la tàbí ní ọ̀túnla tí ó bá sì ní ojú rere ní inú dídùn sí ọ, tí èmi kò bá ránṣẹ́ sí ọ, kí èmi sì jẹ́ kí o mọ̀?

13. Ṣùgbọ́n tí baba mi kò bá ní ìfẹ́ sí pa ọ́ lára, kí Olúwa kí ó dí ìyà jẹ mí, tó bẹ́ẹ̀ àti jù bẹ́ẹ̀ lọ; tí n kò bá jẹ́ kí o mọ̀, kí n sì jẹ́ kí o lọ ní àlàáfíà. Kí Olúwa kí ó pẹ̀lú ù rẹ gẹ́gẹ́ bí ó ti wà pẹ̀lú baba mi.

14. Ṣùgbọ́n fi inú rere àìkùnà hàn mí. Níwọ̀n ìgbà tí mo bá wà láàyè kí wọ́n má ba à pa mí,

15. Má ṣe ké àánú rẹ kúrò lórí ìdílé mi títí láé. Bí Olúwa tilẹ̀ ké gbogbo ọ̀ta Dáfídì kúrò lórí ilẹ̀.”

16. Nígbà náà ni Jónátanìf bá ilé Dáfídì dá májẹ̀mú wí pé, “Olúwa yóò pe àwọn àti Dáfídì láti sírò”

17. Jónátanì mú kí Dáfídì tún ìbúra ṣe nítorí ìfẹ́ tí ó ní síi, nítorí tí ó fẹ́ ẹ gẹ́gẹ́ bí ó ti fẹ́ràn ara rẹ̀.

18. Nígbà náà ni Jónátanì wí fún Dáfídì pé, “Lọ́la ní ibi àsè ìbẹ̀rẹ̀ oṣù tuntun, a ó ò fẹ́ ọ kù, nítorí àyè rẹ yóò ṣófo.

19. Ní ọ̀túnla lọ́wọ́ alẹ́ lọ sí bi tí o sá pamọ́ sí nígbà tí ìṣòro yìí bẹ̀rẹ̀, kí o sì dúró níbi òkúta Ésélù.

20. Èmi yóò ta ọfà mẹ́ta sí ẹ̀gbẹ́ ibẹ̀, gẹ́gẹ́ bí i pé mo ta á sí àmì ibìkan.

21. Èmi yóò rán ọmọdékùnrin kan èmi yóò wí fún un wí pé, ‘Lọ, kí o lọ wá ọfà náà.’ Tí mo bá sọ fún-un wí pé, ‘wò ó, ọfà wọ̀nyí wà ní ibi báyìí ní ẹ̀gbẹ́ ẹ̀ rẹ;’ kó wọn wá síbí kí o sì wá, nítorí pé, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti wà ní ààyè, o wà ní àlàáfíà; kò sí ewú.

22. Ṣùgbọ́n tí mo bá sọ fún ọmọdékùnrin náà pé, ‘wò ó, àwọn ọfà náà kọjá níwájú rẹ;’ nígbà náà, o gbọdọ̀ lọ, nítorí Olúwa ti rán ọ jáde lọ.

23. Nípa ọ̀rọ̀ tí èmi àti ìwọ jọ sọ, rántí Olúwa jẹ́ ẹlẹ́rìí láàrin ìwọ àti èmi títí láéláé.”

24. Bẹ́ẹ̀ ni Dáfídì sá pamọ́ sínú pápá. Nígbà tí àṣè ìbẹ̀rẹ̀ oṣù tuntun sì dé, ọba sì jókòó láti jẹun.

25. Ó sì jókòó gẹ́gẹ́ bí ipò o rẹ̀ ní ibi tí ó máa ń ijòkòó lórí ìjòkó tí ó wà lẹ́gbẹ̀ ẹ́ ògiri, ní òdìkejì Jónátanì, Ábínérì sì jókòó ti Ṣọ́ọ̀lù, ṣùgbọ́n àyè Dáfídì sì ṣófo.

26. Ṣọ́ọ̀lù kò sọ nǹkan kan ní ọjọ́ náà, nítorí ó rò pé, “Nǹkan kan ti ṣẹlẹ̀ sí Dáfídì láti jẹ́ kí ó di aláìmọ́ lótìítọ́ ó jẹ́ aláìmọ́.”

27. Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kejì, ní ọjọ́ kejì oṣù, ààyè Dáfídì sì tún ṣófo. Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù wí fún ọmọ rẹ̀ Jónátanì pé, “Kí ni ó dé tí ọmọ Jésè kò fi wá síbi oúnjẹ, lánàá àti lónìí?”

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 20