Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 19:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ṣọ́ọ̀lù sọ fún Jónátanì ọmọ rẹ̀ àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé kí wọ́n pa Dáfídì. Ṣùgbọ́n Jónátanì fẹ́ràn Dáfídì púpọ̀

2. Ó sì kìlọ̀ fún un pé, “Baba mi Ṣọ́ọ̀lù wá ọ̀nà láti pa ọ́, kíyèsí ara rẹ di òwúrọ̀ ọ̀la; lọ sí ibi ìkọ̀kọ̀, kí o sì sá pamọ́ sí ibẹ̀.

3. Èmi yóò jáde lọ láti dúró ní ọ̀dọ̀ baba mi ní orí pápá níbi tí ó wà. Èmi yóò sọ̀rọ̀ fún un nípa à rẹ, èmi yóò sì sọ ohun tí òun bá wí fún ọ.”

4. Jónátanì sọ̀rọ̀ rere nípa Dáfídì fún Ṣọ́ọ̀lù baba rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Má ṣe jẹ́ kí ọba kí ó ṣe ohun tí kò dára fún Dáfídì ìránṣẹ́ rẹ̀; nítorí tí kò ṣẹ̀ ọ́, ohun tí ó sì ṣe pé ọ púpọ̀.

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 19