Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 17:47-52 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

47. Gbogbo àwọn tí ó péjọ níbí ni yóò mọ̀ pé kì í ṣe nípa ọ̀kọ̀ tàbí idà ni Olúwa fi ń gbàlà; ogun náà ti Olúwa ni, yóò sì fi gbogbo yín lé ọwọ́ ọ wa.”

48. Bí Fílístínì ṣe súnmọ́ iwájú láti pàdé e rẹ̀. Dáfídì yára sáré sí oun náà láti pàdé e rẹ̀.

49. Ó ti ọwọ́ sí àpò rẹ̀ ó sì mú òkúta jáde wá ó sì fì í, ó sì jù ú sí ọ̀kọ́kán iwájú orí Fílístínì. Òkúta náà sì wọ̀ ọ́ níwájú orí, ó sì ṣubú ó sì dojúbolẹ̀ ní orí ilẹ̀.

50. Dáfídì yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun lórí Fílístínì pẹ̀lú kànnàkànnà àti òkúta, láìsí idà ní ọwọ́ rẹ̀, ó lu Fílístínì ó sì pa á.

51. Dáfídì sì sáré ó sì dúró lórí rẹ̀. Ó sì mú idà Fílístínì, ó sì fà á yọ nínú àkọ̀ ọ rẹ̀. Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti pa á tan, ó sì gé orí i rẹ̀ pẹ̀lú idà.Nígbà tí àwọn ará Fílístínì rí i wí pé akọni wọn ti kú, wọ́n yípadà wọ́n sì sálọ.

52. Nígbà náà, àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì àti ti Júdà súnmọ́ iwájú pẹ̀lú ariwo, wọ́n sì lépa àwọn ará Fílístínì dé ẹnu ibodè Gátì àti títí dé ẹnu ibodè Ékírónì. Àwọn tí ó kú wà káàkiri ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà Ṣáráímù àti títí dé ọ̀nà Gátì àti Ékírónì.

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 17