Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 17:29-47 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

29. Dáfídì wí pé, “Kí ni mo ṣe nísinsìn yìí? Ǹjẹ́ mo lè sọ̀rọ̀ bí?”

30. Ó sì yípadà sí ẹlòmíràn, ó sì ń sọ̀rọ̀ kán náà, ọkùnrin náà sì dáhùn bí ti ẹni ìṣáájú.

31. Àwọn ènìyàn gbọ́ ohun tí Dáfídì sọ wọ́n sọ fún Ṣọ́ọ̀lù, Ṣọ́ọ̀lù sì ránṣẹ́ sí i.

32. Dáfídì sọ fún Ṣọ́ọ̀lù pé, “Kí ẹnikẹ́ni má ṣe ba ọkàn jẹ́ nítorí Fílístínì yìí, ìránṣẹ́ rẹ yóò lọ láti bá a jà.”

33. Ṣọ́ọ̀lù sì dáhùn pé, “Ìwọ kò tó láti jáde lọ pàdé ogun Fílístínì yìí àti láti bá a jà; ọmọdé ni iwọ́, òun sì ti ń jagun láti ìgbà èwe rẹ̀ wá.”

34. Ṣùgbọ́n Dáfídì sọ fún Ṣọ́ọ̀lù pé, “Ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ ti ń tọ́jú agbo àgùntàn baba rẹ̀. Nígbà tí kìnìún tàbí àmọ̀tẹ́kùn bá wá láti wá gbé àgùntàn láti inú igbó.

35. Mo sá tẹ̀lé e, mo lù ú, mo sì gba àgùntàn náà kúrò lẹ́nu rẹ̀. Nígbà tí ó kọjú sí mi, mo fi irun rẹ̀ gbá a mú, mo sì lù ú mo sì pa á.

36. Ìránṣẹ́ rẹ ti pa kìnnìún àti àmọ̀tẹ́kùn, aláìkọlà Fílístínì yìí yóò jẹ́ ọ̀kan lára wọn, nítorí ó ti pe ogun Ọlọ́run alààyè ní ìjà.

37. Olúwa tí ó gbà mí kúrò lọ́wọ́ ìhàlẹ̀ kìnnìún àti ti ìhàlẹ̀ àmọ̀tẹ́kùn yóò gbà mí kúrò lọ́wọ́ Fílístínì yìí.”Ṣọ́ọ̀lù wí fún Dáfídì pé, “Lọ kí Olúwa wà pẹ̀lú ù rẹ.”

38. Ṣọ́ọ̀lù fi aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ̀ wọ Dáfídì, ó wọ̀ ọ́ ní aṣọ ìhámọ́ra ogun, ó sì fi ìbòrí idẹ kan bò ó ní orí.

39. Dáfídì si di idà rẹ̀ mọ́ àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ̀ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní rìn káàkiri nítorí wí pé kò mọ́ ọ lára.Ó sọ fún Ṣọ́ọ̀lù pé, “Èmi kò le wọ èyí lọ, kò mọ́ mi lára.” Ó sì bọ́ wọn kúrò.

40. Nígbà náà, ó sì mú ọ̀pá a rẹ̀ lọ́wọ́, ó ṣa òkúta dídán márùn ún létí odò, ó kó wọn sí àpò olùṣọ́ àgùntàn tí ó wà lọ́wọ́ ọ rẹ̀ pẹ̀lú kànnàkànnà.

41. Lákòókò yìí, Fílístínì pẹ̀lú ẹni tí ń gbé ìhámọ́ra ààbò wà níwájú rẹ̀, ó ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ Dáfídì.

42. Ó wo Dáfídì láti òkè délẹ̀, ó sì rí i wí pé ọmọ kékeré kùnrin ni, ó pọ́n ó sì lẹ́wà lójú, ó sì kẹ́gàn an rẹ̀.

43. Ó sì wí fún Dáfídì pé, “Ṣé ajá ni mí ni? Tí o fi tọ̀ mí wá pẹ̀lú ọ̀pá?” Fílístínì sì gbé Dáfídì bú pẹ̀lú Ọlọ́run rẹ̀.

44. Ó wí pé, “Wá níbí, èmi yóò fi ẹran ara rẹ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run jẹ àti fún àwọn ẹranko tí ó wà nínú igbó!”

45. Dáfídì sì wí fún Fílístínì pé, “Ìwọ dojú ìjà kọ mí pẹ̀lú idà, ọ̀kọ̀ àti ọfà, ṣùgbọ́n èmi wá sí ọ̀dọ̀ rẹ pẹ̀lú orúkọ Olúwa àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì tí ìwọ tí gàn.

46. Lónìí yìí ni Olúwa yóò fi ọ́ lé mi lọ́wọ́, èmi yóò sì pa ọ́, èmi yóò sì gé orí ì rẹ. Lónìí èmi yóò fi òkú ogun Fílístínì fún ẹyẹ ojú ọ̀run àti fún ẹranko ìgbó, gbogbo ayé yóò sì mọ̀ pé Ọlọ́run wà ní Ísírẹ́lì.

47. Gbogbo àwọn tí ó péjọ níbí ni yóò mọ̀ pé kì í ṣe nípa ọ̀kọ̀ tàbí idà ni Olúwa fi ń gbàlà; ogun náà ti Olúwa ni, yóò sì fi gbogbo yín lé ọwọ́ ọ wa.”

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 17