Nígbà náà, ó sì mú ọ̀pá a rẹ̀ lọ́wọ́, ó ṣa òkúta dídán márùn ún létí odò, ó kó wọn sí àpò olùṣọ́ àgùntàn tí ó wà lọ́wọ́ ọ rẹ̀ pẹ̀lú kànnàkànnà.