Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 15:6-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Nígbà náà ni ó wí fún àwọn Kénáítì pé, “Ẹ lọ, kúrò ní Ámálékì kí èmi má ba à run yín pẹ̀lú wọn; nítorí ẹ̀yin fi àánú hàn fún gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n gòkè ti Éjíbítì wá.” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn Kénáítì lọ kúrò láàrin àwọn Ámálékì.

7. Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù kọlu àwọn Ámálékì láti Háfílà dé Súrì, tí ó fi dé ìlà oòrùn Éjíbítì.

8. Ó sì mú Ágágì ọba Ámálékì láàyè, ó sì fi idà rẹ̀ kọlu gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀.

9. Ṣùgbọ́n Ṣọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ dá Ágágì sí àti èyí tí ó dára jùlọ nínú àgùntàn àti màlúù àti ọ̀dọ́ àgùntàn àbọ́pa àti gbogbo nǹkan tó dára. Wọ́n kò sì fẹ́ pa àwọn wọ̀nyí run pátapáta ṣùgbọ́n gbogbo nǹkan tí kò dára tí kò sì ní láárí ni wọ́n parun pátapáta.

10. Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Sámúẹ́lì wá pé:

11. “Èmi káànú gidigidi pé mo fi Ṣọ́ọ̀lù jọba, nítorí pé ó ti yípadà kúrò lẹ́yìn mi, kò sì pa ọ̀rọ̀ mi mọ́.” Inú Sámúẹ́lì sì bàjẹ́ gidigidi, ó sì képe Olúwa ní gbogbo òru náà.

12. Ní òwúrọ̀ kùtùkùtù Sámúẹ́lì sì dìde láti lọ pàdé Ṣọ́ọ̀lù, ṣùgbọ́n wọ́n sọ fún un pé, “Ṣọ́ọ̀lù ti wá sí Kámẹ́lì. Ó ti kọ́ ibìkan fún ara rẹ̀ níbẹ̀, ó sì ti yípadà, ó sì ti sọ̀kalẹ̀ lọ sí Gílígálì.”

13. Nígbà tí Sámúẹ́lì sì dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, Ṣọ́ọ̀lù sì wí fún un pé, “Olúwa bùkún fún ọ, mo ti ṣe ohun tí Olúwa pa láṣẹ.”

14. Ṣùgbọ́n Sámúẹ́lì wí pé, “Èwo wá ni igbe àgùntàn tí mo ń gbọ́ ní etí mi? Kí ni igbe màlúù ti mo ń gbọ́ yìí?”

15. Ṣọ́ọ̀lù sì dáhùn pé, “Àwọn ọmọ ogun ní o mú wọn láti Ámálékì wá, wọ́n dá àwọn àgùntàn, àti màlúù tí ó dára jùlọ sí láti fi rúbọ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ, ṣùgbọ́n a pa àwọn tó kù run pátapáta.”

16. Sámúẹ́lì sí wí fún Ṣọ́ọ̀lù pé, “Dákẹ́ ná, jẹ́ kí èmi kí ó sọ ohun tí Olúwa wí fún mi ní alẹ́ àná fún ọ.”Sọ́ọ̀lù sì wí pé, “Sọ fún mi.”

17. Sámúẹ́lì sì wí pé, “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ fi ìgbà kan kéré lójú ara rẹ, ǹjẹ́ ìwọ kò ha di olórí ẹ̀yà Ísírẹ́lì? Olúwa fi àmì òróró yàn ọ́ ní ọba lórí Ísírẹ́lì.

18. Ó sì rán ọ níṣẹ́ wí pé, ‘Lọ, kí o sì pa àwọn ènìyàn búburú ará Ámálékì run pátapáta; gbógun tì wọ́n títí ìwọ yóò fi run wọ́n.’

19. Èéṣe tí ìwọ kò fi gbọ́ ti Olúwa? Èéṣe tí ìwọ fi sáré sí ìkógun tí o sì ṣe búburú níwájú Olúwa?”

20. Ṣọ́ọ̀lù sì wí fún Sámúẹ́lì pé, “Ṣùgbọ́n èmi ti ṣe ìgbọ́rán sí Olúwa, èmi sì ti lọ ní ọ̀nà tí Olúwa rán mi. Mo sì ti pa àwọn ará Ámálékì run pátapáta, mo sì ti mú Ágágì ọba wọn padà wá.

21. Àwọn ọmọ ogun ti mú àgùntàn àti màlúù lára ìkógùn èyí tí ó dára láti fi fún Olúwa láti fi rúbọ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ ní Gílígálì.”

22. Ṣùgbọ́n Sámúẹ́lì dáhùn pé,“Ǹjẹ́ Olúwa ní inú dídùn sí ọrẹ sísun àti ẹbọju kí a ṣe ohun tí Olúwa wí?Ìgbọ́ràn sàn ju ẹbọ lọ,ìfetísílẹ̀ sì sàn ju ọ̀rá àgbò lọ.

23. Nítorí pé ìṣọ̀tẹ̀ dàbí ẹ̀ṣẹ̀ àfọ̀ṣẹ,àti ìgbéraga bí ẹ̀ṣẹ̀ ìbọ̀rìṣà.Nítorí tí ìwọ ti kọ ọ̀rọ̀ Olúwa,Òun sì ti kọ̀ ọ́ ní ọba.”

24. Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù wí fún Sámúẹ́lì pé, “Èmi ti ṣẹ̀. Mo ti rú òfin Olúwa àti ọ̀rọ̀ rẹ̀. Èmi sì bẹ̀rù àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ni èmi sì gba ohùn wọn gbọ́.

25. Mo bẹ̀ ọ́ nísinsìn yìí, dárí ẹ̀ṣẹ̀ mi jìn, kí ó sì yípadà pẹ̀lú mi, kí èmi kí ó lè sin Olúwa.”

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 15