Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 8:41-54 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

41. “Níti àwọn àlejò tí kì í ṣe Ísírẹ́lì ènìyàn rẹ, ṣùgbọ́n tí ó ti ilẹ̀ òkèèrè jáde wá nítorí orúkọ rẹ,

42. nítorí tí àwọn ènìyàn yóò gbọ́ orúkọ ńlá rẹ, àti ọwọ́ agbára rẹ, àti nínà apá rẹ, nígbà tí ó bá sì wá, tí ó sì gbàdúrà sí ìhà ilé yìí,

43. nígbà náà ni kí o gbọ́ láti ọ̀run wá, ní ibùgbé rẹ, kí o sì ṣe gbogbo èyí tí àlejò náà yóò bèèrè lọ́wọ́ rẹ, kí gbogbo ènìyàn ní ayé lè mọ orúkọ rẹ, kí wọn kí ó sì máa bẹ̀rù rẹ, gẹ́gẹ́ bí Ísírẹ́lì, ènìyàn rẹ ti ṣe, kí wọn kí ó sì le mọ̀ pé orúkọ rẹ ni a fi pe ilé yìí tí mo kọ́.

44. “Nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ bá jáde lọ sí ogun sí àwọn ọ̀ta wọn, níbikíbi tí ìwọ bá rán wọn, nígbà tí wọ́n bá gbàdúrà sí Olúwa sí ìhà ìlú tí ìwọ ti yàn àti síhà ilé tí mo ti kọ́ fún orúkọ rẹ,

45. nígbà náà ni kí o gbọ́ àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ wọn láti ọ̀run, kí o sì mú ọ̀rọ̀ wọn dúró.

46. “Nígbà tí wọ́n bá ṣẹ̀ sí ọ, nítorí kò sí ẹnìkan tí kì í ṣẹ̀, tí ìwọ sì bínú sí wọn, tí ìwọ sì fi wọ́n lé ọ̀tá lọ́wọ́, tí ó kó wọn ní ìgbékùn lọ sí ilẹ̀ wọn, jínjìnnà tàbí nítòòsí;

47. bí wọ́n bá ní ìyípadà ọkàn ní ilẹ̀ níbi tí a kó wọn ní ìgbèkùn lọ, tí wọ́n bá sì ronúpìwàdà, tí wọ́n sì bẹ̀bẹ̀ sí ọ ní ilẹ̀ àwọn tí ó kó wọn ní ìgbékùn lọ, wí pé, ‘Àwa ti ṣẹ̀, àwa ti ṣe ohun tí kò tọ́, àwa ti ṣe búburú’;

48. bí wọ́n bá sì fi gbogbo àyà àti gbogbo ọkàn wọn yípadà sí ọ, ní ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn, tí ó kó wọn ní ìgbèkùn lọ, tí wọ́n sì gbàdúrà sí ọ sí ìhà ilẹ̀ wọn tí ìwọ ti fi fún àwọn baba wọn, Ìlú tí ìwọ ti yàn, àti ilé tí èmi kọ́ fún orúkọ rẹ;

49. Nígbà náà ni kí ìwọ kí ó gbọ́ àdúrà wọn àti ẹ̀bẹ̀ wọn ní ọ̀run, ní ibùgbé rẹ, kí o sì mú ọ̀ràn wọn dúró.

50. Kí o sì dáríjìn àwọn ènìyàn rẹ, tí wọ́n ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ; dárí gbogbo ìrékọjá wọn tí wọ́n ṣe sí ọ jì, kí o sì bá àwọn tí ó kó wọn ní ìgbèkùn lọ wí, kí wọn kí ó lè ṣàánú fún wọn;

51. nítorí ènìyàn rẹ àti ìní rẹ ni wọ́n, àwọn ẹni tí ìwọ ti mú ti Éjíbítì jáde wá, láti inú irin ìléru.

52. “Jẹ́ kí ojú rẹ sí sí ẹ̀bẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ, àti sí ẹ̀bẹ̀ àwọn ènìyàn rẹ Ísírẹ́lì, kí o sì tẹ́tí sílẹ̀ sí wọn nígbà tí wọ́n bá kégbe sí ọ.

53. Nítorí tí ìwọ ti yà wọ́n kúrò nínú gbogbo orílẹ̀ èdè ayé, láti máa jẹ́ ìní rẹ, bí ìwọ ti sọ lati ọwọ́ Móṣè ìránṣẹ́ rẹ, nígbà tí ìwọ Olúwa Ọlọ́run mú àwọn baba wa ti Éjíbítì jáde wá.”

54. Nígbà tí Sólómónì ti parí gbogbo àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ yìí sí Olúwa tán, ó dìde kúrò lórí eékún rẹ̀ níwájú pẹpẹ Olúwa níbi tí ó ti kúnlẹ̀ tí ó sì na ọwọ́ rẹ̀ sí òkè ọ̀run

Ka pipe ipin 1 Ọba 8