Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 7:34-51 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

34. Ẹṣẹ̀ kọ̀ọ̀kan sì ní ìfẹsẹ̀tẹ̀ mẹ́rin, ọ̀kan ní igun kọ̀ọ̀kan, tí ó yọrí jáde láti ẹṣẹ̀.

35. Lókè ẹṣẹ̀ náà ni àyíká kan wà tí ó jẹ́ ààbọ̀ ìgbọ̀nwọ́ ní jíjìn. Ẹ̀gbẹ́ etí rẹ̀ àti àlàfo ọ̀nà àárin rẹ̀ ni a ṣo mọ́ òkè ẹsẹ̀ náà.

36. Ó sì gbẹ́ àwòrán kérúbù, kìnnìún àti igi ọ̀pẹ sára ìhà orí rẹ̀ àti sára àlàfo ọ̀nà àárin, ní gbogbo ibi tí àyè wà, pẹ̀lú iṣẹ́ ọ̀ṣọ́ yíkákiri.

37. Báyìí ni ó ṣe ṣe àwọn ẹsẹ̀ mẹ́wẹ̀ẹ̀wàá. Wọ́n sì gbẹ́ gbogbo wọn bákan náà, ìwọ̀n kan náà àti títóbi kan náà.

38. Nígbà náà ni ó ṣe agbádá idẹ mẹ́wàá, ọ̀kọ̀ọ̀kan gbà tó ogójì ìwọ̀n Bátì, ó sì wọn ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin, lórí ọ̀kọ̀ọ̀kan ẹsẹ̀ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá náà ni agbádá kọ̀ọ̀kan wà.

39. Ó sì fi ẹsẹ̀ márùn ún sí apá ọ̀tún ìhà gúṣù ilé náà àti márùn ún sí apá òsì ìhà àríwá. Ó sì gbé agbádá ńlá ka apá ọ̀tún, ní apá ìlà oòrùn sí ìdojúkọ gúṣù ilé náà.

40. Ó sì tún ṣe ìkòkò, àti ọkọ́ àti àwo kòtò.Bẹ́ẹ̀ ni Hírámù sì parí gbogbo iṣẹ́ tí ó ṣe fún ilé Olúwa fún Sólómónì ọba:

41. Àwọn ọ̀wọ̀n méjì;Ọpọ́n méjì ìparí tí ó wà lókè àwọn ọ̀wọ̀n iṣẹ́;àwọn méjì ní láti bo ọpọ́n méjì ìparí tí ń bẹ lókè àwọn ọ̀wọ̀n;

42. Irínwó (400) pómégíránátè fún iṣẹ́ àwọn méjì, ọ̀wọ́ méjì pómégíránátè fún iṣẹ́ àwọn kan láti bo àwọn ọpọ́n méjì ìparí tí ń bẹ lókè àwọn ọ̀wọ̀n;

43. Ẹṣẹ̀ mẹ́wàá pẹ̀lú agbádá mẹ́wàá wọn;

44. Agbada ńlá náà, àti màlúù méjìlá tí ó wà lábẹ́ rẹ̀;

45. Ìkòkò, ọkọ́ àti àwo kòtò.Gbogbo ohun èlò wọ̀nyí tí Hírámù ṣe fún Sólómónì ọba nítorí iṣẹ́ Olúwa sì jẹ́ idẹ dídán.

46. Ọba sì dá wọn ní ilẹ̀ amọ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jọ́dánì lágbedeméjì Ṣúkótì àti Ṣárítanì.

47. Sólómónì sì jọ̀wọ́ gbogbo nǹkan wọ̀nyí láìwọ̀n, nítorí tí wọ́n pọ̀ jù; bẹ́ẹ̀ ni a kò sì mọ ìwọ̀n idẹ.

48. Sólómónì sì tún ṣe gbogbo ohun ọ̀ṣọ́ tí ń ṣe ti ilé Olúwa pẹ̀lú:pẹpẹ wúrà;tabílì wúrà lórí èyí tí àkàrà ìfihàn gbé wà;

49. Ọ̀pá fìtílà kìkì wúrà, márùn-ún ní apá ọ̀tún àti márùn ún ní apá òsì, níwájú ibi mímọ́ jùlọ; ìtànná ewéko;fìtílà àti ẹ̀mú wúrà;

50. Ọpọ́n kìkì wúrà, àlùmágàjí fìtílà, àti àwo kòtò, àti ṣíbí àti àwo tùràrí ti wúrà dáradára;àti àgbékọ́ wúrà fún ilẹ̀kùn inú ilé ibi mímọ́ jùlọ àti fún ilẹ̀kùn ilé náà, àní ti tẹ́ḿpìlì.

51. Nígbà tí gbogbo iṣẹ́ tí Sólómónì ọba ṣe fún ilé Olúwa parí, ó mú gbogbo nǹkan tí Dáfídì baba rẹ̀ ti yà sí mímọ́ wá; fàdákà, wúrà àti ohun èlò, ó sì fi wọ́n sínú ìṣúra ilé Olúwa.

Ka pipe ipin 1 Ọba 7