Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 20:6-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Ṣùgbọ́n ní ìwòyí ọ̀la Èmi yóò rán àwọn ìránṣẹ́ mi sí ọ láti wá ilé rẹ wò àti ilé àwọn ìránṣẹ́ rẹ. Wọn yóò gba gbogbo ohun tí ó bá dára lójú rẹ, wọn yóò sì kó o lọ.’ ”

7. Nígbà náà ni ọba Ísírẹ́lì pe gbogbo àwọn àgbà ìlú, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ wo bí ọkùnrin yìí ti ń fẹ́ ìyọnu! Nígbà tí ó ránṣẹ́ fún àwọn aya mi, àti fún àwọn ọmọ mi, àti fún fàdákà mi, àti fún wúrà mi, èmi kò sì fi dù ú.”

8. Àwọn àgbà àti gbogbo ènìyàn dá a lóhùn pé, “Má se fi etí sí tirẹ̀ tàbí kí o gbà fún un.”

9. Nígbà náà ni ó sọ fún àwọn oníṣẹ́ Bẹni-Hádádì pé, “Sọ fún Olúwa mi ọba pé, ‘Ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò ṣe ohun gbogbo tí ó ránṣẹ́ fún látètèkọ́ṣe, ṣùgbọ́n nǹkan yìí ni èmi kò le ṣe.’ ” Wọ́n padà lọ, wọ́n sì mú èsì padà wá fún Bẹni-hádádì.

10. Bẹni-Hádádì sì tún rán oníṣẹ́ mìíràn sí Áhábù wí pé, “kí àwọn òrìṣà kí ó ṣe bẹ́ẹ̀ sí mi àti jù bẹ́ẹ̀ lọ pẹ̀lú bí eekuru Samáríà yóò tó fún ìkúnwọ́ fún gbogbo ènìyàn tí ń tẹ̀lé mi.”

11. Ọba Ísírẹ́lì sì dáhùn wí pé, “Sọ fún un pé: ‘Má jẹ́ kí ẹni tí ń hámọ́rà halẹ̀ bí ẹni tí ń bọ́ ọ sílẹ̀.’ ”

12. Bẹni-Hádádì sì gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí nigbà tí òun àti àwọn ọba ń mu ọtí nínú àgọ́ wọn, ó sì pàṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wí pé, “Ẹ tẹgun sí ìlú náà.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ṣe tan láti kọlu ìlú náà.

13. Sì kíyèsí i, wòlíì kan tọ Áhábù ọba Ísírẹ́lì wá, ó sì wí pé, “Báyìí ni Olúwa wí: ‘Ìwọ rí gbogbo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun yìí? Èmi yóò fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́ lónìí, nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.’ ”

14. Áhábù sì béèrè pé, “Ṣùgbọ́n ta ni yóò ṣe èyí?”Wòlíì náà sì dáhùn wí pé, “Ìwọ ni yóò ṣe é.”

15. Nígbà náà ni Áhábù ka àwọn ìjòyè kéékèèkéé ìgbéríko, wọ́n sì jẹ́ igba ó lé méjìlélọ́gbọ̀n. (232) Nígbà náà ni ó sì kó gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó kù jọ, gbogbo wọn sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin. (700)

Ka pipe ipin 1 Ọba 20