Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 20:14-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Áhábù sì béèrè pé, “Ṣùgbọ́n ta ni yóò ṣe èyí?”Wòlíì náà sì dáhùn wí pé, “Ìwọ ni yóò ṣe é.”

15. Nígbà náà ni Áhábù ka àwọn ìjòyè kéékèèkéé ìgbéríko, wọ́n sì jẹ́ igba ó lé méjìlélọ́gbọ̀n. (232) Nígbà náà ni ó sì kó gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó kù jọ, gbogbo wọn sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin. (700)

16. Wọ́n sì jáde lọ ní ọ̀sán gangan, nígbà tí Bẹni-Hádádì àti àwọn ọba méjìlélọ́gbọ̀n tí ń ràn án lọ́wọ́ ń mu àmúpara nínú àgọ́.

17. Àwọn ìjòyè kékèké ìgbéríko tètè kọ́ jáde lọ.Bẹni-Hádádì sì ránṣẹ́ jáde, wọ́n sì sọ fún un wí pé, “Àwọn ọkùnrin ń ti Samáríà jáde wá.”

18. Ó sì wí pé, “Bí wọ́n bá bá ti àlàáfíà jáde wá, ẹ mú wọn láàyè; bí ti ogun ni wọ́n bá bá jáde, ẹ mú wọn láàyè.”

19. Àwọn ìjòyè kékèké wọ̀nyí ti àwọn ìjòyè ìgbéríko jáde ti ìlú wá, àti ogun tí ó tẹ̀lé wọn.

20. Olúkúlùkù sì pa ọkùnrin kọ̀ọ̀kan. Àwọn ará Árámù sì sá, Ísírẹ́lì sì lépa wọn. Ṣùgbọ́n Bẹni-Hádádì ọba Árámù sì sálà lórí ẹsin pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́sin.

21. Ọba Ísírẹ́lì sì jáde lọ, ó sì kọlu àwọn ẹsin àti kẹ̀kẹ́, ó pa àwọn ará Árámù ní ọ̀pọ̀lọpọ̀.

22. Lẹ́yìn náà, wòlíì náà sì wá sọ́dọ̀ ọba Ísírẹ́lì, ó sì wí pé, “Lọ, mú ara rẹ gírí, kí o sì mọ̀, kí o sì wo ohun tí ìwọ yóò ṣe, nítorí ní àmọ́dún ọba Árámù yóò tún gòkè tọ̀ ọ́ wá.”

23. Àwọn ìránṣẹ́ ọba Árámù sì wí fún un pé, “Ọlọ́run wọn, Ọlọ́run òkè ni. Ìdí nìyìí tí wọ́n ṣe ní agbára jù wá lọ. Ṣùgbọ́n bí a bá bá wọn jà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, àwa yóò ní agbára jù wọ́n lọ dájúdájú.

24. Nǹkan yìí ni kí o sì ṣe: Mú àwọn ọba kúrò, olúkúlùkù kúrò ní ipò rẹ̀, kí o sì fi olórí ogun sí ipò wọn.

25. Kí o sì tún kó ogun jọ fún ara rẹ bí èyí tí ó ti sọnù; ẹṣin fún ẹṣin, kẹ̀kẹ́ fún kẹ̀kẹ́; kí a bá lè bá Ísírẹ́lì jà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀. Nítòótọ́ àwa yóò ní agbára jù wọ́n lọ.” Ó sì gba ti wọn, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀.

26. Ó sì ṣe ní àmọ́dún, Bẹni-Hádádì ka iye àwọn ará Árámù, ó sì gòkè lọ sí Áfékì, láti bá Ísírẹ́lì jagun.

27. Nígbà tí a sì ka àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n sì pèsè oúnjẹ, wọ́n sì lọ pàdé wọn. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì dó níwájú wọn gẹ́gẹ́ bí agbo ọmọ ewúrẹ́ kékeré méjì, nígbà tí àwọn ará Árámù kún ilẹ̀ náà.

Ka pipe ipin 1 Ọba 20