Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 2:23-37 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. Nígbà náà ni Sólómónì ọba fi Olúwa búra pé: “Kí Ọlọ́run ki ó jẹ mí níyà, àti jù bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú, bí Àdóníjà kò bá ní fi ẹ̀mí rẹ̀ san ìbéèrè yìí!

24. Àti nísinsìnyí, bí ó ti dájú pé Olúwa wà láàyè ẹni tí ó ti mú mi jókòó lórí ìtẹ́ baba mi Dáfídì àti tí ó sì ti kọ́ ilé fún mi bí ó ti ṣèlérí, lónìí ni a ó pa Àdóníjà!”

25. Sólómónì ọba sì pàṣẹ fún Bénáyà ọmọ Jéhóíádà, ó sì kọlu Àdóníjà, ó sì kú.

26. Ọba sì wí fún Ábíátarì àlùfáà pé, “Padà lọ sí pápá rẹ ni Ánátótì, ó yẹ fún ọ láti kú, ṣùgbọ́n èmi kì yóò pa ọ́ nísinsìn yìí, nítorí o ti gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa níwájú Dáfídì baba mi, o sì ti ní ìpín nínú gbogbo ìyà tí baba mi jẹ.”

27. Bẹ́ẹ̀ ni Sólómónì yọ Ábíátarì kúrò nínú iṣẹ́ àlùfáà Olúwa, kí ó lè mú ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó ti sọ nípa ilé Élì ní Ṣílò ṣẹ.

28. Nígbà tí ìròyìn sì dé ọ̀dọ̀ Jóábù, ẹni tí ó ti dìtẹ̀ pẹ̀lú Àdóníjà bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò wà pẹ̀lú Ábúsálómù, ó sì sá lọ sínú àgọ́ Olúwa, ó sì di ìwo pẹpẹ mú.

29. A sì sọ fún Sólómónì ọba pé Jóábù ti sá lọ sínú àgọ́ Olúwa àti pé ó wà ní ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ. Nígbà náà ni Sólómónì pàṣẹ fún Bénáyà ọmọ Johóíadà pé, “Lọ, kí o sì kọlù ú.”

30. Bénáyà sì wọ inú àgọ́ Olúwa, ó sì wí fún Jóábù pé, “Ọba sọ wí pé, Jáde wá.”Ṣùgbọ́n ó dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, Èmi yóò kú níhìn ín.”Bénáyà sì mú èsì fún ọba, “Báyìí ni Jóábù ṣe dá mi lóhùn.”

31. Ọba sì pàṣẹ fún Bénáyà pé, “Ṣe bí ó ti wí. Kọ lù ú, kí o sì sin ín, kí o sì mú ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ mi àti kúrò lọ́dọ̀ ilé bàbá mi, tí Jóábù ti ta sílẹ̀.

32. Olúwa yóò sì san ẹ̀jẹ̀ tí ó ti ta sílẹ̀ padà fún un, nítorí tí ó kọlu ọkùnrin méjì, ó sì fi idà rẹ̀ pa wọ́n, Dáfídì bàbá mi kò sì mọ̀ àwọn méjèèjì ni. Ábínérì ọmọ Nérì olórí ogun Ísírẹ́lì, àti Ámásà ọmọ Jétérì olórí ogun Júdà, wọ́n jẹ́ olódodo, wọ́n sì sàn ju òun fúnrarẹ̀ lọ.

33. Kí ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ wọn wá sórí Jóábù àti sórí irú-ọmọ rẹ̀ títí láé. Ṣùgbọ́n sórí Dáfídì àti irú-ọmọ rẹ̀, sí ilé rẹ̀ àti sí ìtẹ́ rẹ̀, ni kí àlàáfíà Olúwa wà títí láé.”

34. Bẹ́ẹ̀ ni Bénáyà ọmọ Jéhóíádà sì gòkè lọ, ó sì kọlu Jóábù, ó sì pa á, a sì sin ín ní ilẹ̀ ibojì ara rẹ̀ ní ihà.

35. Ọba sì fi Bénáyà ọmọ Jéhóíádà jẹ olórí ogun ní ipò Jóábù àti Sádókù àlùfáà ní ipò Ábíátarì.

36. Nígbà náà ni ọba ránṣẹ́ sí Ṣíméhì ó sì wí fún un pé, “Kọ́ ilé fún ara rẹ ní Jérúsálẹ́mù, kí o sì máa gbé ibẹ̀, ṣùgbọ́n kí o má sì ṣe lọ sí ibòmíràn.

37. Ọjọ́ tí ìwọ bá jáde, tí o sì kọjá pẹ̀tẹ́lẹ̀ Kídírónì, kí ìwọ kí ó mọ̀ dájúdájú pé ìwọ yóò kú; ẹ̀jẹ̀ rẹ yóò sì wà lórí ara rẹ.”

Ka pipe ipin 1 Ọba 2