Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 19:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Áhábù sì sọ gbogbo ohun tí Èlíjà ti ṣe fún Jésébélì àti bí ó ti fi idà pa gbogbo àwọn wòlíì.

2. Nítorí náà Jésébélì rán oníṣẹ́ kan sí Èlíjà wí pé, “Kí àwọn òrìṣà kí ó ṣe sí mi àti jù bẹ́ẹ̀ lọ pẹ̀lú, bí èmi kò bá ṣe ẹ̀mí rẹ bí ọ̀kan nínú wọn ní ìwòyí ọ̀la.”

3. Èlíjà sì bẹ̀rù, ó sá fún ẹ̀mí rẹ̀. Nígbà tí ó sì dé Bíáṣébà ti Júdà, ó sì fi ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ sílẹ̀ níbẹ̀,

4. nígbà tí òun tìkárarẹ̀ sì lọ ní ìrìn ojọ́ kan sí ihà, ó sì wá sí ibi igi ọwọ̀ kan, ó sì jókòó lábẹ́ rẹ̀, ó sì gbàdúrà kí òun bá le kú, wí pé, “Mo ti ní tó, Olúwa, gba ẹ̀mí mi kúrò; nítorí èmi kò sàn ju àwọn baba mi lọ”

5. Nígbà náà ni ó dùbúlẹ̀ lábẹ́ igi, ó sì sùn lọ.Sì wòó, ańgẹ́lì fi ọwọ́ tọ́ ọ, ó sì wí pé, “Dìdé, kí o jẹun.”

6. Ó sì wò ó yíká, àkàrà tí a dín lórí ẹ̀yínná, àti orù-omi wà lẹ́bá orí rẹ̀. Ó sì jẹ, ó sì mu, ó sì tún dùbúlẹ̀.

7. Ańgẹ́lì Olúwa sì tún padà wá lẹ́ẹ̀kejì, ó sì tún fi ọwọ́ tọ́ ọ, ó sì wí pé, “Dìde, kí ó jẹun, nítorí ìrìnàjò náà jìn fún ọ.”

8. Ó si dide, ó sì jẹ, ó mu, o sì fi agbára oúnjẹ yìí lọ ní ogójì ọ̀sán àti ogójì òru sí Hórébù, òkè Ọlọ́run.

9. Níbẹ̀, ó lọ sí ibi ihò òkúta, ó sì wọ̀ níbẹ̀.Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Èlíjà wá wí pé, “Kí ni ìwọ ń ṣe níhìn-ín yìí, Èlíjà?”

Ka pipe ipin 1 Ọba 19