Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 18:40-46 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

40. Nígbà náà ni Èlíjà sì pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ mú àwọn wòlíì Báálì. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọ̀kan nínú wọn kí ó sá lọ!” Wọ́n sì mú wọn, Èlíjà sì mú wọn sọ̀kalẹ̀ sí odò Kíṣónì, ó sì pa wọ́n níbẹ̀.

41. Èlíjà sì wí fún Áhábù pé, “Lọ, jẹ, kí o sì mu, nítorí ìró ọ̀pọ̀lọpọ̀ òjò ń bọ̀.”

42. Bẹ́ẹ̀ ni Áhábù gòkè lọ láti jẹ àti láti mu. Ṣùgbọ́n Èlíjà gun orí òkè Kámẹ́lì lọ ó sì tẹríba, ó sì fi ojú rẹ̀ sí agbede-méjì eékún rẹ̀.

43. Ó sì wí fún ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, “Lọ, kí o sì wo ìhà òkun, òun sì gòkè lọ, ó sì wò.”Ó sì wí pé, “Kò sí nǹkan níbẹ̀.”Ó sì wí pé, “Tún lọ nígbà méje.”

44. Nígbà keje, ìránṣẹ́ náà sì wí pé, “Àwọ̀sánmọ̀ kékeré kan dìde láti inú òkun, gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ ènìyàn.”Èlíjà sì wí pé, “Lọ, kí o sọ fún Áhábù pé, ‘Di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ, kí o sì sọ̀kalẹ̀ lọ, kí òjò ó má ba à dá ọ dúró.’ ”

45. Ó sì ṣe, nígbà díẹ̀ sí i, ọ̀run sì sú fún àwọsánmọ̀, ìjì sì dìde, òjò púpọ̀ sì rọ̀, Áhábù sì gun kẹ̀kẹ́ lọ sí Jésírẹ́lì.

46. Agbára Olúwa sì ń bẹ lára Èlíjà; ó sì di àmùrè ẹ̀gbẹ́ rẹ, ó sì ṣáré níwájú Áhábù títí dé Jésírẹ́lì.

Ka pipe ipin 1 Ọba 18