Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 16:20-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Níti ìyókù ìṣe Ṣímírì, àti ọ̀tẹ̀ rẹ̀ tí ó dì, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Ísiírẹ́lì?

21. Nígbà náà ní àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì dá sí méjì; apákan wọn ń tọ Tíbínì ọmọ Gínátì lẹ́yìn, láti fi í jọba, apákan tókù sì ń tọ Ómírì lẹ́yìn.

22. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn tí ń tọ Ómírì lẹ́yìn borí àwọn tí ń tọ Tíbínì ọmọ Gínátì lẹ́yìn. Bẹ́ẹ̀ ni Tíbínì kú, Ómírì sì jọba.

23. Ní ọdún kọkànlélọ́gbọ̀n Áṣà ọba Júdà, Ómírì bẹ̀rẹ̀ sí ń jọba lórí Ísírẹ́lì, ó sì jọba ní ọdún méjìlá, ọdún mẹ́fà ní Tírisà.

24. Ó sì ra òkè Samáríà lọ́wọ́ Sérérì ní talẹ́ńtì méjì fàdákà, ó sì kọ́ ìlú sórí rẹ̀, ó sì pe ìlú náà ní Samáríà, nípa orúkọ Sémérì, orúkọ ẹni tí ó kọ́kọ́ ni òkè náà.

25. Ṣùgbọ́n Ómírì sì ṣe búburú níwájú Olúwa, Ó sì ṣe búburú ju gbogbo àwọn tí ó wà ṣáájú rẹ̀ lọ.

26. Ó rìn ní gbogbo ọ̀nà Jéróbóámù ọmọ Nébátì àti nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, èyí tí ó ti mú Ísírẹ́lì ṣẹ̀, láti fi ohun asán wọn mú Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì bínú.

27. Ìyòókù ìṣe àti ohun tí ó ṣe, àti agbára rẹ tí ó fi hàn, a kò ha kọ, wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Ísírẹ́lì?

28. Ómírì sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀ a sì sin ín ní Ṣamáríà. Áhábù ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.

29. Ní ọdún kejìdínlógójì Áṣà ọba Júdà, Áhábù ọmọ Ómírì jọba ní Isireli, o si jọba lórí Ísírẹ́lì ní Samáríà ní ọdún méjìlélógún.

30. Áhábù ọmọ Ómírì sì ṣe búburú ní ojú Olúwa ju gbogbo àwọn tí ó wà ṣáájú rẹ̀ lọ.

31. Ó sì ṣe bí ẹni pé ó ṣe ohun kékeré fún un láti máa rìn nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jéróbóámù ọmọ Nébátì, ó sì mú Jésébélì, ọmọbìnrin Étíbáálì, ọba àwọn ará Sídónì ní aya, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ń sin Báálì, ó sì bọ ọ́.

32. Ó sì tẹ́ pẹpẹ kan fún Báálì nínú ilé Báálì tí ó kọ́ sí Samáríà.

33. Áhábù sì tún ṣe ère òrìṣà kan, ó sì ṣe púpọ̀ láti mú Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì bínú ju èyí tí gbogbo ọba Ísírẹ́lì tí ó ti wà ṣáájú rẹ̀ ti ṣe lọ.

34. Ní ìgbà ayé Áhábù, Híélì ará Bétélì kọ́ Jẹ́ríkò. Ó fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lé ilẹ̀ ní Ábírámù, àkọ́bí rẹ, ó sì gbé àwọn ilẹ̀kùn ibodè rẹ̀ kọ́ ní Ṣégúdù àbíkẹ́yìn rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó ti ipa Jóṣúà ọmọ Núnì sọ.

Ka pipe ipin 1 Ọba 16