Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 11:20-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Arábìnrin Tápénésì bí ọmọkùnrin kan fún un tí à ń pe orúkọ rẹ̀ ní Génúbátì, ẹni tí Tápénésì tọ́ dàgbà ní ààfin ọba. Níbẹ̀ ni Génúbátì ń gbé pẹ̀lú àwọn ọmọ Fáráò fún ra rẹ̀.

21. Nígbà tí ó sì wà ní Éjíbítì, Hádádì sì gbọ́ pé Dáfídì ti sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, àti pé Jóábù olórí ogun sì ti kú pẹ̀lú. Nígbà náà ni Hádádì wí fún Fáráò pé, “Jẹ́ kí n lọ, kí èmi kí ó le padà sí ìlú mi.”

22. Fáráò sì wí fún un pé, “Kí ni ìwọ ṣe aláìní níbí, tí ìwọ fi fẹ́ padà lọ sí ìlú rẹ?”Hádádì sì wí pé, “Kò sí nǹkan, ṣùgbọ́n sá à jẹ́ kí èmi kí ó lọ!”

23. Ọlọ́run sì gbé ọ̀ta mìíràn dìde sí Sólómónì, Résónì ọmọ Élíádà, ẹni tí ó ti sá kúrò lọ́dọ̀ Hádádésérì olúwa rẹ̀, ọba Sóbà.

24. Ó sì kó ènìyàn jọ sọ́dọ̀ ara rẹ̀, ó sì di olórí ogun ẹgbẹ́ kan, nígbà tí Dáfídì fi pa ogun Sóbà run; wọ́n sì lọ sí Dámásíkù, wọ́n ń gbé ibẹ̀, wọ́n sì jọba ní Dámásíkù.

25. Résónì sì jẹ́ ọ̀ta Ísírẹ́lì ní gbogbo ọjọ́ Sólómónì, ó ń pa kún ibi ti Hádádì ṣe. Bẹ́ẹ̀ ni Résónì jọba ní Síríà, ó sì sòdì sí Ísírẹ́lì.

26. Bákan náà Jéróbóámù ọmọ Nébátì sì sọ̀tẹ̀ sí ọba. Ó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ Sólómónì, ará Éfúrátì ti Sérédà, ìyá rẹ̀ sì jẹ́ opó, orúkọ rẹ̀ ni Sérúà.

27. Èyí sì ni ìdí tí ó fi sọ̀tẹ̀ sí ọba: Sólómónì kọ́ Mílò, ó sì di ẹ̀yà ìlú Dáfídì baba rẹ̀.

28. Jéróbóámù jẹ́ ọkùnrin alágbára, nígbà tí Sólómónì sì rí bí ọ̀dọ́mọkùnrin náà ti ṣe iṣẹ́ rẹ̀ dáradára, ó fi í ṣe olórí iṣẹ́ ìrú ilé Jóṣẹ́fù.

29. Ó sì ṣe, ní àkókò náà Jéróbóámù ń jáde kúrò ní Jérúsálẹ́mù. Wòlíì Áhíjà ti Ṣílò sì pàdé rẹ̀ lójú ọ̀nà, ó sì wọ agbádá túntún. Àwọn méjèèjì nìkan ni ó sì ń bẹ ní oko,

30. Áhíjà sì gbá agbádá túntún tí ó wọ̀ mú, ó sì fà á ya sí ọ̀nà méjìlá

31. Nígbà náà ni ó sọ fún Jéróbóámù pé, “Mú ọ̀nà mẹ́wàá fún ara rẹ, nítorí báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí pé: ‘Wò ó, èmi yóò fa ìjọba náà ya kúrò ní ọwọ́ Sólómónì, èmi yóò sì fi ẹ̀yà mẹ́wàá fún ọ.

32. Ṣùgbọ́n nítorí ti Dáfídì ìránṣẹ́ mi àti nítorí Jérúsálẹ́mù, ìlú tí mo ti yàn nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì, òun yóò ní ẹ̀yà kan.

Ka pipe ipin 1 Ọba 11