Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 10:5-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Oúnjẹ tí ó wà lórí i tábìlì rẹ̀, ìjókòó àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀, àti ìdúró àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti ìwọṣọ wọn, àwọn agbọ́tí rẹ̀, àti ẹbọ ọrẹ̀ sísun tí ó sun ní ilé Olúwa, kò sì sí ẹ̀mí kan nínú rẹ̀ mọ́!

6. Ó sì wí fún ọba pé, “Òtítọ́ ni ìròyìn tí mo gbọ́ ní orílẹ̀ èdè mi níti iṣẹ́ rẹ àti ọgbọ́n rẹ.

7. Ṣùgbọ́n èmi kò sì gba nǹkan wọ̀nyí gbọ́ títí ìgbà tí mo wá, tí mo sì fi ojú ara mi rí i. Sì kíyèsí i, a kò sọ ìdajì wọn fún mi; ìwọ sì ti fi ọgbọ́n àti ìrora kọjá òkìkí tí mo gbọ́.

8. Báwo ni inú àwọn ènìyàn rẹ yóò ṣe dùn tó! Báwo ni inú dídùn àwọn ìránṣẹ́ rẹ, tí wọ́n ń dúró níwájú rẹ nígbà gbogbo, tí wọ́n sì ń gbọ́ ọgbọ́n rẹ!

9. Ìbùkún ni fún Olúwa Ọlọ́run rẹ, tí ó ní inú dídùn sí ọ, tí ó sì gbé ọ ka orí ìtẹ́ Ísírẹ́lì. Nítorí tí Olúwa fẹ́ràn Ísírẹ́lì títí láé, ni ó ṣe fi ọ́ jọba, láti ṣe ìdájọ́ àti òdodo.”

10. Ó sì fún ọba ní ọgọ́fà (120) talẹ́ńtì wúrà, tùràrí olóòórún dídùn lọ́pọ̀lọpọ̀, àti òkúta iyebíye. Kò sí irú ọ̀pọ̀lọpọ̀ tùràrí tí a mú wá tí ó dà bí irú èyí tí ayaba Ṣébà fi fún Sólómónì ọba.

11. Pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn ọ̀wọ́-ọkọ̀ Hírámù tí ó mú wúrà láti ófírì wá wọ́n mú igi Álúgúmù, ógì Sáńdálì lọ́pọ̀lọpọ̀ àti òkúta oníyebíye láti ófírì wá.

12. Ọba sì fi igi Álúgúmù náà ṣe òpó fún ilé Olúwa àti fún ààfin ọba, àti láti ṣe dùùrù pẹ̀lú àti ohun èlò orin mìíràn fún àwọn akọrin. Irú igi Álúgúmù bẹ́ẹ̀ kò dé mọ́, bẹ́ẹ̀ ni a kò rí wọn títí di òní yìí.

13. Sólómónì ọba sì fún ayaba Ṣébà ní gbogbo ìfẹ́ rẹ̀ àti ohun tí ó béèrè, yàtọ̀ sí èyí tí a fi fún un láti ọwọ́ Sólómónì ọba wa. Nígbà náà ni ó yípadà, ó sì lọ sí ìlú rẹ̀, pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.

14. Ìwọ̀n wúrà tí Sólómónì ń gbà ní ọdún kan sì jẹ́ ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀ta (666) ó lé mẹ́fà talẹ́ńtì wúrà,

15. Láìka èyí tí ó ń gbà lọ́wọ́ àwọn ajẹ́lẹ̀ àti àwọn oníṣòwò, àti ti gbogbo àwọn ọba Árábíà, àti àwọn baálẹ̀ ilẹ̀.

16. Sólómónì ọba sì ṣe igba (200) aṣà wúrà lílù; ẹgbẹ̀ta (600) ṣékélì wúrà ni ó lọ sí asà kan.

17. Ó sì tún ṣe ọ̀ọ́dúrún (300) aṣà wúrà lílù, pẹ̀lú òṣùwọ̀n wúrà mẹ́ta tí ó tàn sí aṣà kọ̀ọ̀kan. Ọba sì kó wọn sí ilé igbó Lébánónì.

Ka pipe ipin 1 Ọba 10