Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 10:12-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Ọba sì fi igi Álúgúmù náà ṣe òpó fún ilé Olúwa àti fún ààfin ọba, àti láti ṣe dùùrù pẹ̀lú àti ohun èlò orin mìíràn fún àwọn akọrin. Irú igi Álúgúmù bẹ́ẹ̀ kò dé mọ́, bẹ́ẹ̀ ni a kò rí wọn títí di òní yìí.

13. Sólómónì ọba sì fún ayaba Ṣébà ní gbogbo ìfẹ́ rẹ̀ àti ohun tí ó béèrè, yàtọ̀ sí èyí tí a fi fún un láti ọwọ́ Sólómónì ọba wa. Nígbà náà ni ó yípadà, ó sì lọ sí ìlú rẹ̀, pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.

14. Ìwọ̀n wúrà tí Sólómónì ń gbà ní ọdún kan sì jẹ́ ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀ta (666) ó lé mẹ́fà talẹ́ńtì wúrà,

15. Láìka èyí tí ó ń gbà lọ́wọ́ àwọn ajẹ́lẹ̀ àti àwọn oníṣòwò, àti ti gbogbo àwọn ọba Árábíà, àti àwọn baálẹ̀ ilẹ̀.

16. Sólómónì ọba sì ṣe igba (200) aṣà wúrà lílù; ẹgbẹ̀ta (600) ṣékélì wúrà ni ó lọ sí asà kan.

17. Ó sì tún ṣe ọ̀ọ́dúrún (300) aṣà wúrà lílù, pẹ̀lú òṣùwọ̀n wúrà mẹ́ta tí ó tàn sí aṣà kọ̀ọ̀kan. Ọba sì kó wọn sí ilé igbó Lébánónì.

18. Nígbà náà ni ọba sì ṣe ìtẹ́ èyín erin ńlá kan, ó sì fi wúrà dídára bò ó.

19. Ìtẹ́ náà sì ní àtẹ̀gùn mẹ́fà, èyín rẹ̀ sì ṣe róbótó lókè. Ní ibi ìjókòó méjèèjì náà ni irọpá wà, pẹ̀lú kìnnìún tí ó dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìkọ̀ọ̀kan wọn.

20. Kìnnìún méjìlá sì dúró níbi àtẹ̀gùn mẹ́fẹ̀ẹ̀fà ọ̀kọ̀kan ní òpin àtẹ̀gùn kọ̀ọ̀kan, kò tí ì sí irú rẹ̀ ní ìjọba kan rí.

21. Gbogbo ohun èlò mímu Sólómónì ọba sì jẹ́ wúrà àti gbogbo ohun èlò ààfin igbó Lébánónì sì jẹ́ kìkì wúrà. Kò sí ìkankan tí a fi fàdákà ṣe, nítorí a kò ka fàdákà sí nǹkankan ní gbogbo ọjọ́ Sólómónì.

22. Ọba sì ní ọkọ̀ Tásísì kan pẹ̀lú ọkọ̀ Hírámù ní òkun. Ẹ̀ẹ̀kan ní ọdún mẹ́ta ni ọkọ̀ Tásísì ń dé, tí ó ń mú wúrà àti fàdákà, eyín-erin àti ìnàkí àti ẹyẹ-ológe wá.

23. Sólómónì ọba sì pọ̀ ní ọrọ̀ àti ní ọgbọ́n ju gbogbo àwọn ọba ayé lọ.

Ka pipe ipin 1 Ọba 10