1. Nígbà tí ayaba Ṣébà gbọ́ òkìkí Sólómónì àti ìbáṣepọ̀ rẹ̀ níti orúkọ Olúwa, ó sì wá láti dán an wò pẹ̀lú ìbéèrè líle.
2. Ó sì wá sí Jérúsálẹ́mù pẹ̀lú ẹgbẹ́ èrò ńlá ńlá, pẹ̀lú ràkúnmí tí ó ru tùràrí, ati ọ̀pọ̀lọpọ̀ wúrà, àti òkúta iyebíye, ó sì wá sí ọ̀dọ̀ Sólómónì, ó sì bá a sọ gbogbo èyí tí ń bẹ ní ọkàn rẹ̀.
3. Sólómónì sì dáhùn gbogbo ìbéèrè rẹ̀; kò sì sí èyí tí ó ṣòro fún ọba láti ṣàlàyé fún un.
4. Nígbà tí ayaba Ṣébà sì rí gbogbo ọgbọ́n Sólómónì àti ààfin tí ó ti kọ́.
5. Oúnjẹ tí ó wà lórí i tábìlì rẹ̀, ìjókòó àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀, àti ìdúró àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti ìwọṣọ wọn, àwọn agbọ́tí rẹ̀, àti ẹbọ ọrẹ̀ sísun tí ó sun ní ilé Olúwa, kò sì sí ẹ̀mí kan nínú rẹ̀ mọ́!