Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 9:11-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Áṣáríyà ọmọ Hílíkíyà, ọmọ Mésúlámù, ọmọ Ṣádókù, ọmọ Méráíótù, ọmọ Áhítúbì, onísẹ́ tí ó ń bojútó ilé Ọlọ́run;

12. Ádáyà ọmọ Jéróhámù, ọmọ Páṣúrì, ọmọ Málíkíjà; àti Másáì ọmọ Ádíélì, ọmọ Jáhíṣérà, ọmọ Mésúlámù ọmọ Méṣílémítì, ọmọ Ímérì

13. Àwọn àlùfáà, tí wọ́n jẹ́ àwọn olórí àwọn ìdílé, tí ó jẹ́ ẹgbẹ̀sán ó dín méjì (1,760). Wọ́n jẹ́ alágbára ọkùnrin, tí wọ́n lè dúró fún iṣẹ́ ìránṣẹ́ nínú ilé Ọlọ́run.

14. Níti àwọn ará Léfì:Ṣémáíà ọmọ Hásíhúbì, ọmọ Ásíríkámù, ọmọ Háṣábíà ará Mérárì:

15. Bákíbákárì, Héréṣì, Gálálì àti Mátaníyà, ọmọ Míkà, ọmọ Ṣíkírì, ọmọ Ásáfù;

16. Ọbadíà ọmọ Ṣémáíà, ọmọ Gálálì, ọmọ Jédútúnì; àti Bérékíà ọmọ Ásà, ọmọ Élíkánà, Tí ó ń gbé nínú àwọn ìlú àwọn ará Nétófá.

17. Àwọn Olùtọ́jú Ẹnu Ọ̀nà:Ṣálúmù, Ákúbù, Tálímónì, Áhímánì àti arákùnrin wọn, Ṣálúmì olóyè wọn,

18. ti wà ní ipò ìdúró ní ẹnu ọ̀nà ọba ní apá ìhà ìlà oòrùn títí di àkókò yí. Wọ̀nyí ni àwọn olùtọ́jú ẹnu ọ̀nà tí ó jẹ́ ti ìpàgọ́ àwọn ará Léfì.

19. Ṣálúmì ọmọ kórè ọmọ Ébíásáfì, ọmọ kórà, àti àwọn olùtọ́jú ẹnu ọ̀nà ẹlẹ́gbẹ́ Rẹ̀. Láti ìdílé Rẹ̀ (àwọn ará kórà) ni ó dúró fún ṣíṣọ́ ìlóró ẹnu ọ̀nà àgọ́ gẹ́gẹ́ bí baba wọn ti ń dúró fún ṣíṣọ́ à bá wọlé ibùgbé Olúwa.

20. Ní ìgbà àkọ́kọ́ fíníhásì ọmọ Élíásérì jẹ́ olórí fún àwọn olùtọ́jú ẹnu ọ̀nà, Olúwa sì wà pẹ̀lú Rẹ̀.

21. Ṣékáríà, ọmọ Méṣélémíà jẹ́ Olùtọ́jú ẹnu ọ̀nà ní à bá wọlé sí àgọ́ ibi ìpàdé.

22. Gbogbo Rẹ̀ lápapọ̀, àwọn tí a yàn láti jẹ́ olùtọ́jú ẹnu ọ̀nà ní àwọn ìlóró ẹnu ọ̀nà jẹ́ ìgba o lé méjìlá (212). A kòmọ̀-ọ́n fún ìràntí nípa ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn ní àwọn ìletò wọn. Àwọn olùtọ́jú ẹnu ọ̀nà ni a ti yàn sí ipò ìgbàgbọ́ wọn láti ọ̀dọ̀ Dáfídì àti Ṣámúẹ́lì aríran.

23. Àwọn àti àtẹ̀lé wọn ni ó wà fún ṣíṣọ́ ẹnu ọ̀nà ilé Olúwa ilé tí a pè ní àgọ́.

24. Àwọn olùtọ́ju ẹnu ọ̀nà wà ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin: ìlà oòrùn, ìwọ̀ oòrùn àríwá àti gúsù.

25. Àwọn arákùnrin wọn ní àwọn ìletò wọn ní láti wá ní àkókò dé àkókò láti pín isẹ́ ìsìn wọn fún àkókò ọjọ́ méje.

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 9