Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 5:19-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Wọ́n sì bá àwọn ọmọ Hágárì jagun, pẹ̀lú Jétúrì, àti Néfísì àti Nádábù.

20. Nígbà tí wọ́n sì rí ìrànlọ́wọ́ gbà si, a sì fi àwọn ọmọ Hágárì lé wọn lọ́wọ́, àti gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú wọn; nítorí ti wọn képe Ọlọ́run ní ogun náà, òun sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn; nítorí tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ wọn lé e.

21. Wọ́n sì kó ẹran ọ̀sìn wọn lọ; ràkunmí ẹgbàámẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n àti àgùntàn ọ̀kẹ́ méjìlá ó lé ẹgbàárùnún, àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ẹgbàá, àti ènìyàn ọ̀kẹ́ márùn ún.

22. Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó ṣubú tí a pa, nítorí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ogun náà, wọ́n sì jókòó ní ipò wọn títí di ìgbà ìkólọ sí ìgbékùn.

23. Àwọn ọmọkùnrin ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè ń gbé ní ilẹ̀ náà: wọ́n bí sí i láti Básánì títí dé Báálì-hérímónì, àti Ṣénírì àti títí dé òkè Hérímónì.

24. Wọ̀nyí sì ni àwọn olórí ilé àwọn baba wọn. Éférì, Ísì, Élíélì, Ásíríélì, Jérémáíà, Hódáfíà àti Jáhídíélì àwọn alágbára akọni ọkùnrin, ọkùnrin olókìkí, àti olórí ilé àwọn baba wọn.

25. Wọ́n sì ṣẹ̀ sí Ọlọ́run àwọn baba wọn, wọ́n sì se àgbérè tọ àwọn ọlọ́run ènìyàn ilẹ̀ náà lẹ́yìn, tí Ọlọ́run ti parun ní iwájú wọn.

26. Nítorí náà Ọlọ́run Ísírẹ́lì ru ẹmi Púlù ọba Ásíríà sókè, ó si kó wọn lọ, àní àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti àwọn ọmọ Gádì, àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè, ó sì kó wọn wá sí Hálà, àti Hábórì, àti Hárà, àti sí ọ̀dọ̀ Gósánì; títí dí òní yìí.

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 5