Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 27:23-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. Dáfídì kò kọ iye àwọn ọkùnrin náà ní ogún ọdún sẹ́yìn tàbí dín nítori Olúwa ti ṣe ìlerí lati ṣe Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí iye ìràwọ̀ ojú ọ̀run.

24. Jóábù ọmọ Ṣérúyà bẹ̀rẹ̀ sí ní kàwọ́n, ṣùgbọ́n kò parí kíkà wọ́n nítorí, ìbínú dé sórí àwọn Ísírẹ́lì nipaṣẹ̀ kíka iye àti iye náà, a kò kọọ́ sínu ìwé ìtàn ayé ti ọba Dáfídì.

25. Áṣímáfétì ọmọ Ádíélì wà ní ìdí ilé ìṣúra ti ọba. Jónátanì ọmọ Úṣíà wà ní ìdí ilé ìṣúra ní iwájú agbègbè nínú àwọn ìlú, àwọn ìlètò àti àwọn ilé ìṣọ́.

26. Ésírì ọmọ kélúbì wà ní ìdí àwọn òṣìṣẹ́ lórí pápá, tí wọ́n ń ko ilẹ̀ náà.

27. Ṣíméhì ará Rámátì wà ní ìdí àwọn ọgbà àjàrà.Ṣábídì ará Ṣífímì wà ní ìdí mímú jáde ti èṣo àjàrà fún ọpọ́n ńlá tí a ń fi ọ̀tún èso àjàrà sí.

28. Bálì Hánánì ará Gédérì wà ní ìdi Ólífì àti àwọn igi Ṣíkámórè ní apá ìhà ìwọ̀ oòrùn àwọn ní ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀tẹ́lẹ̀.Jóáṣì wà ní ìdí fífún ni ní òróró Ólífì.

29. Ṣítíráì ará Ṣárónì wà ní idi fífi ọwọ́ ẹran jẹ ko ní Ṣárónì.Ṣáfátì ọmọ Ádíláì wà ní ìdí àwọn ọ̀wọ́-ẹran ní àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀.

30. Óbílì ará Íṣímáélì wà ní ìdí àwọn ìbákasíẹ.Jéhidéísì ará Mérónótì wà ní ìdí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.

31. Jáṣíṣì ará Hágírì wà ní ìdi àwọn agbo-ẹran.Gbogbo wọ̀nyí ni àwọn oníṣẹ́ tí wọ́n wà ní ìdí ẹrù ọba Dáfídì.

32. Jónátanì, arákùnrin Dáfídì jẹ́ olùdámọ̀ràn, ọkùnrin onímọ̀ àti akọ̀wé. Jéhíélì ọmọ Hákímónì bojútó àwọn ọmọ ọba.

33. Áhítófélì jẹ́ olùdámọ̀ràn ọba.Húsáì ará Áríkì jẹ́ ọ̀rẹ́ ọba.

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 27