Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 24:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Àwọn wọ̀nyí sì ni pínpín àwọn ọmọ Árónì:Àwọn ọmọ Árónì ni Nádábù, Ábíhù, Élíásérì àti Ítamárì.

2. Ṣùgbọ́n Nádábù àti Ábíhù kú kí ó tó di wí pé baba wọn kú, wọn kò sì ní àwọn ọmọ; Bẹ́ẹ̀ ni Élíásérì àti Ítamárì sì ṣe gẹ́gẹ́ bí àlùfáà.

3. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ṣádókì ọmọ Élíásérì àti Áhímélékì ọmọ Ítamárì, Dáfídì sì yà wọ́n nípa nínú ìpín fún ìyàsọ́tọ̀ àwọn iṣẹ́ ìsìn wọn.

4. A rí ọ̀pọ̀ àwọn olórí lára àwọn ọmọ Élíásérì ju lára àwọn ọmọ Ítamárì lọ, wọ́n sì pín wọn lẹ́sẹ lẹ́sẹ: mẹ́rindínlógún (16) olórí láti ìdílé ọmọ Élíásérì ìran wọn àti olórí méjọ ìdílé láti ara àwọn ọmọ Ítamárì.

5. Wọ́n sì pín wọn lótìítọ́ nípa yíya ìpín, nítorí àwọn olórí ibi mímọ́ àti àwọn olorí ilé Ọlọ́run wà láàrin àwọn ọmọ méjèèjì Élíásérì àti Ìtamárì.

6. Ṣémáíà ọmọ Nétanélì, akọ̀wé ọ̀kan lára àwọn ọmọ Léfì sì kọ orúkọ wọn níwájú ọba àti àwọn ìjòyè: Ṣádókù Àlùfáà, Áhímélékì ọmọ Ábíátarì àti olórí ìdílé àwọn àlùfáà tí a mú láti ọ̀dọ̀ Éléásári àti ọ̀kan láti ọ̀dọ̀ Ítamárì.

7. Ìpín èkíní jáde sí Jéhóíáríbù,èkejì sí Jédáià,

8. Ẹlẹ́kẹta sì ni Hárímù,ẹ̀kẹ́rin sì ní Ṣéórímù,

9. Ẹ̀karùn-ún sì ni Maíkíyà,ẹlẹkẹ́fà sì ni Míjámínì,

10. Ẹ̀kẹ́je sì ni Hakósì,ẹlẹ́kẹ́jọ sí ni Ábíjà,

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 24