Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 23:21-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Àwọn ọmọ Mérárì:Máhílì àti Músì.Àwọn ọmọ Máhílì:Élíásárì àti Kísì.

22. Élíásérì sì kú pẹ̀lú Àìní àwọn ọmọkùnrin: Ó ní ọmọbìnrin nìkan. Àwọn ọmọ ẹ̀gbọ́n, àwọn ọmọ Kísì, sì fẹ́ wọn.

23. Àwọn ọmọ Músì:Málì, Édérì àti Jérímótì mẹ́ta ni gbogbo wọn.

24. Àwọn wọ̀nyí sì ni ọmọ Léfì bí ìdílé wọn. Olórí ìdílé gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti fi orúkọ sílẹ̀ lábẹ́ orúkọ wọn, ó sì kà wọn ní ẹyọ kọ̀ọ̀kan, wí pé, àwọn òṣìṣẹ́ tí ó jẹ́ ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tí ń ṣiṣẹ́ ìsìn nínú ilé Olúwa

25. Nítorí pé Dáfídì ti sọ pé Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ti fi ìsinmi fún àwọn ènìyàn tí ó kù tí sì ń gbé Jérúsálẹ́mù títí láéláé.

26. Àwọn ọmọ Léfì kò sì tún ru àgọ́ tàbí ọ̀kankan lára àwọn ohun èlò tí wọ́n ń lò níbi ìsìn Rẹ̀.

27. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ìkẹyìn Dáfídì sí, àwọn ọmọ Léfì, wọ́n sì kà wọ́n, bẹ̀rẹ̀ láti orí àwọn ọmọ ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ.

28. Iṣẹ́ àwọn ọmọ Léfì ni láti ran àwọn ọmọ Árónì lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ wọn fún ti ilé Olúwa: láti wà lábẹ́ ìkáwọ́ agbára ìlú, àti ẹ̀gbẹ́ ilé, àti ìwẹ̀nùmọ́ ti gbogbo ohun ìyàsọ́tọ̀ àti ṣíṣe ohun tìí ṣe iṣẹ́ ìsìn nínú ilé Olúwa.

29. Wọ́n sì wà ní ìkáwọ́ àkàrà tí wọ́n mú jáde láti orí tábìlì, àti ìyẹ̀fun fún ẹbọ ọrẹ, àti aláìwú pẹ̀tẹ̀, àti fún dídùn àti èyí tí a pòpọ̀, àti gbogbo onírúurú ìwọ̀n àti wíwọ̀n àti òṣùnwọ̀n.

30. Wọ́n sì gbọdọ̀ dúró ní gbogbo òwúrọ̀ láti dúpẹ́ àti láti yin Olúwa. Wọ́n sì gbọdọ̀ ṣe irú kan náà ní àsálẹ́.

31. Ní gbàkúgbà ẹbọ ọrẹ sísun ni wọ́n fi fún Olúwa ní ọjọ́ ìsinmi àti ní àsìkò oṣù tuntun àti ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì tí a paláṣẹ. Wọ́n gbọdọ̀ sìn níwájú Olúwa lójojúmọ́ ní iye tó yẹ àti ní ọ̀nà tí a ti paláṣẹ fún wọn.

32. Bẹ́ẹ̀ ni nígbà náà, àwọn ọmọ Léfì gbé ìgbékalẹ̀ jáde fún ìpàdé àgọ́, fún ibi mímọ́ àti, lábẹ́ àwọn arákùnrin àwọn ọmọ Árónì fún ìsìn ilé Olúwa.

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 23