Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 21:21-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Nígbà náà Dáfídì sì súnmọ́, Nígbà tí Órínánì sì wò tí ó sì rí, ó sì kúrò ní ilẹ̀ ìpakà ó sì doju bolẹ̀ níwájú Dáfídì pẹ̀lú ojú Rẹ̀ ní ilẹ̀.

22. Dáfídì sì wí fún un pé, “Jẹ́ kí èmi kí ó ni ibi ìpakà rẹ kí èmi kí ó sì lè kọ́ pẹpẹ fún Olúwa, kí àjàkálẹ̀-àrùn lórí àwọn ènìyàn lè dúró. Tàá fún mi ní iye owó kíkún.”

23. Órínánì ni ó sọ fún Dáfídì pé, “Gbà á! Jẹ́ kí Olúwa ọba mi kí ó ṣe ohun tí ó dára lójú Rẹ̀. Woó, èmí yóò fún ọ ní àwọn màlúù fún ẹbọ ọrẹ ṣiṣun, àti ohun èlò ìpakà fún igi, àti ọkà fún ọrẹ oúnjẹ. Èmi yóò fun ọ ní gbogbo èyí.”

24. Ṣùgbọ́n ọba Dáfídì dá Órínánì lóhùn pé, “Rárá, mo wà lórí àti san iye owó rẹ ní pípé, èmi kò sì ní mú fún Olúwa èyí tí ó jẹ́ tìrẹ, tàbí láti rú ẹbọ ọrẹ sísun tí kò ná mi ní ohun kan.”

25. Bẹ́ẹ̀ ni Dáfídì san ẹgbẹ̀ta ṣékélì wúrà fún Órínánì nípa ìwọ̀n fún ibẹ̀ náà.

26. Dáfídì sì tẹ́ pẹpẹ fún Olúwa níbẹ̀ ó sì ní ẹbọ ọrẹ sísun àti ẹbọ ọrẹ àlàáfíà. Ó sì pe orúkọ Olúwa, Olúwa sì da lóhùn pẹ̀lú iná láti òkè ọ̀run lórí pẹpẹ fún ẹbọ ọrẹ ṣíṣun.

27. Nígbà náà Olúwa sọ̀rọ̀ sí ańgẹ́lì, ó sì gbé idà padà bọ̀ sínú àkọ̀ Rẹ̀.

28. Ní àkókò náà nígbà tí Dáfídì sì rí wí pé Olúwa ti dá a lóhùn lórí ilẹ̀ ìpakà ti Órínán ará Jébúsì, ó sì rú ẹbọ ọrẹ sísun níbẹ̀.

29. Àgọ́ Olúwa tí Mósè ti ṣe ní ihà, àti pẹpẹ ẹbọ ọrẹ ṣíṣun wà lórí ibi gíga ní Gíbíónì ní àkókò náà.

30. Ṣùgbọ́n Dáfídì kò lè lọ ṣíwájú Rẹ̀ láti béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, nítorí tí ó bẹ̀rù nípa idà ọwọ́ ańgẹ́lì Olúwa.

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 21